Nǹkan ṣe! Wọ́n ju gbajúmọ̀ ọmọọba Èkó sẹ́wọ̀n n'Ílọrin lórí ẹ̀sùn 'Yahoo-Yahoo' - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, September 22, 2021

Nǹkan ṣe! Wọ́n ju gbajúmọ̀ ọmọọba Èkó sẹ́wọ̀n n'Ílọrin lórí ẹ̀sùn 'Yahoo-Yahoo'


Onidajọ Sikiru Oyinloye ti ile-ẹjọ giga to wa nilu Ilọrin, ipinlẹ Kwara ti ju gbajumọ ọmọọba kan nijọba ibilẹ Koṣọfẹ, ipinlẹ Eko, Oyekan Abdulbaqqi Adedoyin sẹwọn oṣu mẹfa gbako, pẹlu iṣẹ aṣekara lori ẹsun jibiti ori ayelujara, ti ọpọ awọn eeyan tun mọ si Yahoo-Yahoo.
 
Ileeṣẹ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo kumọkumọ lorilẹ-ede yii, iyẹn Economic and Financial Crimes Commission (EFCC) la gbọ pe o fẹsun kan Oyekan, ati ọrẹ rẹ kan, Oni Stephen Oluwafẹranmi niwaju ile-ẹjọ wi pe awọn mejeeji n lu awọn alaimọkan ni jibiti lati ori ayelujara pẹlu ifẹ ẹtan.

Agbẹjọro EFCC, Andrew Akoja nigba to n tako Oyekan, ọmọ ọdun marundinlọgbọn, ati Oni, toun jẹ ọmọ bibi ilu Ileṣa nipinlẹ Oṣun niwaju Onidajọ Akinloye sọ pe ọpọ owo ati dukia ni wọn ti gba.
 
Niwaju ile-ẹjọ ọhun lawọn mejeeji ti jẹwọ pe lotitọ ni, ati pe awọn gba wi pe awọn jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn.
 

Akoja sọ pe oriṣiriṣi iwadii lawọn ṣe pẹlu ẹri aridaju, ko to di pe wọn lọ ko wọn. O lawọn ti gba awọn irinṣẹ wọn bii foonu olowo iyebiye, kọmputa alagbeeka ati awọn atẹjiṣẹ loriṣiriṣi ti wọn fi n lu jibiti wọn gẹgẹ bi ẹri tawọn ni lọwọ.
 
Onidajọ Oyinloye nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ paṣẹ pe ki Oyekan lọ fi ẹwọn oṣu mẹfa pere gbara tabi ko san owo itanran, ẹgbẹ lọna aadọjọ {N150,000} naira, bẹẹ si ni ko gbagbe gbogbo nnkan ti wọn gba lọwọ ẹ patapata sapo ijọba.
 
Ni ti Oni, Onidajọ naa paṣẹ pe koun lọ fi ẹwọn ọdun kan gbako gbara tabi ko san owo itanran, to jẹ ẹgbẹrun lọna ọọdunrun ati aadọta {N350,000} naira.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI