Nítorí ẹ̀sun jìbìtì, wọ́n ju akẹ́kọ̀ọ́ méjì sẹ́wọ̀n ọdún kọ̀ọ̀kan n'Ílọrin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, September 10, 2021

Nítorí ẹ̀sun jìbìtì, wọ́n ju akẹ́kọ̀ọ́ méjì sẹ́wọ̀n ọdún kọ̀ọ̀kan n'Ílọrin


Ile-ẹjọ giga tilu Ilọrin, nipinlẹ Kwara ti ju awọn akẹkọọ meji kan, Ọlamilekan Ezekiel Adebayọ ati Ibrahim Najeeb Ọmọtọṣhọ ṣewọn lori ẹsun jibiti ori ayelujara ti a mọ si Yahoo-Yahoo.
 
Onidajo Sikiru Oyinloye lo sọ Adebayọ, akẹkọọ fasiti ipinlẹ Kwara to wa nilu Malete ati Ọmọtọṣhọ toun jẹ akẹkọọ ile ẹkọ gbogboniṣe tipinlẹ Kwara to wa nilu Ilọrin sẹwọn naa.

Ileeṣẹ to n gbogun ti iwa jibiti lorilẹ-ede yii, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC, ẹka tilu Ilọrin lo foju awọn mejeeji ba ile-ẹjọ, nibi ti wọn fẹsun to nii ṣe pẹlu ifẹ ẹtan ori ayelujara kan wọn.
 
Innocent Mbachie to jẹ agbefọba nigba to n sọrọ sọ pe ki Onidajọ naa fi ẹwọn ta awọn mejeeji lọrẹ lati jiya ẹṣẹ wọn, ki wọn si le kẹkọọ siwaju sii nipa bi ọdọ ṣe n ṣiṣẹ ti ko ni jibiti ninu. 
 
Onidajọ Oyinloye nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ sọ pe awọn ẹri toun ri gba, ninu ẹsun ti wọn fi kan awọn mejeeji kọja ohun ti wọn le sọ pe irọ ni, nitori otitọ pọnbele ni.
 
O ju Adebayọ sẹwọn ọdun kan gbako tabi ko san owo itanran, ẹgbẹrun lọna ọgọrun naira, bẹẹ si ni ko da owo igba dọla to lu jibiti rẹ pada sapo ijọba orilẹ-ede yii.
 
Bakan naa lo ju Ọmọtọṣhọ sẹwọn ọdun kan gbako tabi ko san owo itanran ti ko din ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira, bẹẹ si ni ko da gbogbo nnkan to lu jibiti rẹ, to fi mọ foonu ti wọn gba lọwọ ẹ pada sapo ijọba orilẹ-ede yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI