Ó tán o! Mukaila, ayédèrú Olúwo dèrò àtìmọ̀lé l'Abẹ́òkúta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, September 10, 2021

Ó tán o! Mukaila, ayédèrú Olúwo dèrò àtìmọ̀lé l'Abẹ́òkúta

 
Laarọ oni, ọjọ Ẹti, Furaide lọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun tẹ ọkunrin kan to n pe ara rẹ ni Oluwo ilu Ijẹja nilu Abẹokuta ipinlẹ naa, iyẹn Ọgbẹni Mukaila Akinwande.
 
Gẹgẹ bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ ṣe sọ, wọn ni ile ọkunrin naa to wa lagbegbe Ijẹja, ijọba ibilẹ Abẹokuta South lawọn ọlọpaa Ibara ti lọ gbe e, lori bo ṣe tapa si aṣẹ ile-ẹjọ.
 
Bẹ o ba gbagbe, lọjọ kẹwaa, oṣu kẹjọ to kọja ni ile-ẹjọ giga tipinlẹ Ogun labẹ Onidajọ Ogunfowora paṣẹ fun Mukaila Akinwande lati yee pe ara rẹ ni Oluwo ilu Ijẹja mọ, titi digba ti ẹjọ naa yoo fi yanju.

 
AWIKONKO gbọ pe bi ile-ẹjọ naa ṣe gbe aṣẹ yii kalẹ ni wọn sọ pe Mukaila Akinwande lọ yọ aworan oye Oluwo to wa niwaju ita ile ẹ kuro, ṣugbọn ti wọn ni ko pẹ to tun pada gbe aworan naa pada sibẹ.
 
Latigba yii la gbọ pe awọn eeyan ti bẹrẹ si i kilọ fun un pe ko dẹkun lilo awọn nnkan to le jẹ ki wọn maa pe e ni Oluwo ilu Ijẹja, lati ma ba a ko ba ara rẹ nipa titapa si aṣẹ ile-ẹjọ.
 
Bakan naa la gbọ pe mọto jiipu KIA alawọ pupa ti Mukaila n gbe kaakiri lo so aworan Oluwo mọ, to si jẹ pe gbogbo ibi to ba de lo ti n farahan gẹgẹ bi Oluwo ilu Ijẹja.
 
AWIKONKO gbọ pe ṣe ni ọrọ bẹyin yọ fun Mukaila Akinwande lonii, nigba ti wọn lawọn ọlọpaa lọ gbe e nile ẹ lai wọ bata ati aṣọ.
 
Lara awọn to fiṣẹlẹ naa to AWIKONKO leti fi ye wa pe pẹlu ẹbẹ lawọn ọlọpaa fi gba Mukaila laaye lati wọ aṣọ ati bata rẹ, ti wọn si lọ tii mọle.
 
Bi iroyin naa ṣe jade sita la gbọ pe awọn agbaagba ilu ti wọn fẹran rẹ dide lati lọ ba a bẹbẹ, to si ṣeleri wi pe oun ko tun jẹ pe ara oun ni Oluwo ilu Ijẹja mọ.
 
Lẹyin ọpọlọpọ ẹbẹ lawọn ọlọpaa ni ko tọwọ bọwe adehun lati fi ye wọn pe oun ko tun ni tapa si ofin ati aṣẹ ile-ẹjọ mọ, nipa pipe ara rẹ ni Oluwo ilu Ijẹja.

Gbogbo akitiyan lati ba agbẹnusọ fawọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi sọrọ lori iṣẹlẹ naa lo ja si pabo titi dasiko ti a pari akojọpọ iroyin yii.

Bakan naa la ko tii ri Mukaila ba sọrọ lati gbọ tẹnu ẹ.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI