Nítorí ìdàgbàsókè ni ìjọba ṣe n yá owó - APC jẹ́wọ́ fún PDP - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, September 16, 2021

Nítorí ìdàgbàsókè ni ìjọba ṣe n yá owó - APC jẹ́wọ́ fún PDP


Ẹgbẹ oṣelu App Progressives Congress, APC ti jẹ ko ye ẹgbẹ alatako Peoples Democratic Party, PDP wi pe nitori idagbasoke orilẹ-ede Naijiria nijọba Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe n ya awọn owo ti wọn n ya kaakiri.
 
Wọn ni gbogbo awọn akanṣẹ iṣẹ idagbasoke to n lọ kaakiri orilẹ-ede yii nijọba n wa ọna lati tete pari wọn, ki eto ọrọ aje ile tubọ ni idagbasoke alailẹgbẹ, bẹẹ si ni yoo tun pese iṣẹ, eyi ti yoo din iṣẹ ati oṣi ku.

Siwaju sii ni wọn tun sọ pe asiko yii ko dabi asiko iṣejọba PDP to jẹ pe ṣe ni wọn kan an ko owo ti wọn n ya jẹ, ati pe awọn owo tijọba Buhari n ya yii, lati fi rii pe eto iṣunna ọdun 2021  wa si imuṣẹ lai ni idiwọ kankan ninu.
 
Sẹnetọ John James Akpanudoedehe lo sọ eyi di mimọ, to si ni asiko iṣakoso PDP ni wọn lọ ya owo lati fi ṣagbatẹru ina mọnamọna lorilẹ-ede yii, ati lati fi ra awọn nnkan ija oloro ti wọn yoo fi gbogun ti awọn agbebọn, ṣugbọn to sọ pe ṣe ni wọn ṣe owo naa kumọkumọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI