Aarẹ orilẹ-ede yii, Muhammadu Buhari ti gba iṣẹ lọwọ awọn minisita meji lojiji, o ni wọn ko kun oju oṣuwọn to lori iṣẹ ti wọn gbe le wọn lọwọ.
Minisita fọrọ iṣẹ agbẹ ati ọgbin, Mohammed Sabo Nanono, ati minisita fọrọ ina mọnamọna, Maman Saleh lawọn ti Buhair da duro.
AWIKONKO gbọ pe loju ẹsẹ ni Aarẹ Buhari ti gbe iṣẹ wọn fun minisita fọrọ eto ayika, Mohammed Mahmoud Abubakar ati minisita fọrọ iṣẹ ati ilegbe, Abubakar Aliyu.
AWIKONKO gbọ pe loju ẹsẹ ni Aarẹ Buhari ti gbe iṣẹ wọn fun minisita fọrọ eto ayika, Mohammed Mahmoud Abubakar ati minisita fọrọ iṣẹ ati ilegbe, Abubakar Aliyu.
Ogbẹni Fẹmi Adeṣina to jẹ agbẹnusọ Aarẹ Buhari lori ọrọ eto iroyin ati ipolongo lo fi eyi lede lọsan oni, Ọjọru, Wẹside.
No comments:
Post a Comment