Kò sáàyè láti fẹran jẹko l'Ondo, Akérédolú buwọ́ lu ìwé òfin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, August 31, 2021

Kò sáàyè láti fẹran jẹko l'Ondo, Akérédolú buwọ́ lu ìwé òfin


Gomina Oluwarotimi Akeredolu tipinlẹ Ondo loni, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee ti bu ọwọ lu iwe ofin lati dena fifi ẹran jẹko kaakiri ipinlẹ naa, to si ni ijiya nbẹ fẹnikẹni tọwọ ba tẹ wi pe o fẹran rẹ jẹko kaakiri.
 
Igbesẹ yii waye lẹyin bi oṣu meji tawọn gomina ilẹ Yoruba fẹnuko wi pe awọn ko nii gba fifi ẹran jẹko kaakiri ipinlẹ wọn, iyẹn nibi ipade ti wọn ṣe lọjọ karun-un, oṣu keje to kọja.
 
Bẹ o ba gbagbe, lọsẹ diẹ sẹyin ni Aarẹ Muhammadu Buhari sọ pe ki gbogbo awọn ipinlẹ marundinlọgbọn orilẹ-ede yii ṣe agbeyẹwo awọn ibudo tawọn Fulani darandaran yoo ti maa fẹran jeko, ki wọn si pese aaye ti ko din ni 368, nibi ti wọn yoo ti maa fi ẹran jẹko lai ni idiwọ tabi idena.
 
Nibi ipade tawọn gomina ilẹ Yoruba ṣe loṣu to kọja ni wọn ti fẹnuko pe wọn gbọdọ buwọ lu iwe ofin lati dena fifi ẹran jẹko lawọn ipinlẹ onikalu laaarin ọjọ naa si ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹsan, ọdun yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI