Wàhálà ẹgbẹ́ òṣèlú PDP tún n peléke síi ní Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, September 25, 2021

Wàhálà ẹgbẹ́ òṣèlú PDP tún n peléke síi ní Kwara


Pẹlu nnkan to ṣẹlẹ nipinlẹ kwara lonii, ọjọ Satide, Abamẹta, afaimọ ni ko ma jẹ pe ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP lorilẹ-ede Naijiria yoo pada di ohun igbagbe patapata, pẹlu bo ṣe jẹ ojoojumọ lawọn ọmọ ẹgbẹ n koju ija sira wọn.
 
Nibi ipade gbogboogbo ẹgbẹ naa to waye lonii, ọjọ karundinlọgbọn la ti gbọ pe ṣe ni awọn agbaagba ati alẹnulọrọ ninu ẹgbẹ naa ko yọju sibẹ.
 
Bẹ o ba gbagbe, kii ṣe ahesọ wi pe ẹgbẹ PDP ti pin si meji nipinlẹ naa, ati awọn ipinlẹ kọọkan lorilẹ-ede yii, eyi ti ko jẹ ki imọ wọn ṣọkan.
 
Ko si nnkan meji ti wọn lo jẹ ki awọn eeyan, paapaa awọn alẹnulọrọ ẹgbẹ naa yago fun ipade gbogboogbo ti wọn ṣe lonii, bi ko ṣe ti aawọ ti wọn lo wa laaarin aarẹ ile igbimọ aṣofin agba ana, Bukọla Saraki ati minisita tẹlẹri, Abubakar Sulaiman.
 
Awọn agbaagba mejeeji yii la gbọ pe wọn n fi agba oṣelu han ara wọn, ti wọn si ni gbogbo igba lawọn ọmọlẹyin wọn n koju ija sira wọn.
 
Lara awọn ọmọ ẹyin Sulaiman ṣaaju ohun to ṣẹlẹ lonii ti sọ pe ki awọn oloye ẹgbẹ naa ti wọn ti n ṣakoso lati ọdun 2018 kọwe fipo silẹ, nitori pe ọdun mẹrin wọn ti pe, ti wọn si n leri wi pe awọn yoo gbe wọn lọ sile-ẹjọ.

AWIKONKO gbọ pe ipade gbogboogbo ti wọn pe lonii, ko lọ bo ṣe yẹ, eyi to jẹ ki wọn ṣee bo ṣe gba, ti onikaluku wọn si gba ibi ti wọn ti wa lọ.
 
A tiẹ gbọ pe nibi ipade naa ni wọn ti n pe awọn agbaagba inu ẹgbẹ kọọkan, lati mọ idi ti wọn ko fi yọju, ṣugbọn ti wọn sọ pe pupọ ninu wọn ni ko gbe foonu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI