AbdulRazaq ṣàbẹ̀wò sìlú Ìgbàjà, ó bá kábíyèsí lálejò, bẹ́ẹ̀ ló tún wo àkànṣe iṣẹ́ tó n lọ lọ́wọ́ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, October 30, 2021

AbdulRazaq ṣàbẹ̀wò sìlú Ìgbàjà, ó bá kábíyèsí lálejò, bẹ́ẹ̀ ló tún wo àkànṣe iṣẹ́ tó n lọ lọ́wọ́


Ọjọ abẹwo nla l'Ọjọru, Wẹside to kọja jẹ fun ijọba ipinlẹ Kwara, iyẹn lori bi Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ṣe ṣabẹwo sawọn ibi to ṣe gboogi ti akanṣe iṣẹ ti n lọ lọwọ, paapaa julọ aafin Kabiyesi.
 
Ṣe ni ẹsẹ ko gbero rara nigba ti Gomina AbdulRazaaq wọ ilu ti wọn n pe ni Igbaja, nibi tawọn eeyan ti bẹrẹ sii fo fun ayọ wi pe gomina alaanu mẹkunnu ti de.
 
Lara awọn ibi ti gomina AbdulRazaq kọkọ lọ ni Aafin Elese tilu Igbaja, Ọba Ahmẹd Awuni Babalọla Arepo kẹta, to wa nijọba ibilẹ Ifẹlodun.
 
Lẹyin rẹ lo ṣẹṣẹ tẹsiwaju lati lọ yẹ ibi ti iṣẹ de duro ni ileeṣẹ omi igbalode ti wọn n kọ lọwọ, iyẹn Igbaja waterworks.
 
Diẹ ree lara fọto abẹwo naa:Bo ṣe kuro nibẹ lo tun gba ọsibitu Cottage lọ lati wo bi nnkan ṣe n lọ si nibẹ, to bawọn to wa nibẹ sọrọ itunnu ti yoo fọkan wọn balẹ labẹ iṣakoso rẹ.
 
Lẹyin eyi lo tun ṣabẹwo si ile-ẹkọ ti wọn ti n kọ nipa iṣegun oyinbo, iyẹn Kwara State College of Nursing to wa ni Oke-Ode, ijọba ibilẹ Ifẹlodun bakan naa.
 
Diẹ tun ree lara awọn fọto abẹwo naa fun igbadun yin.
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI