Nítorí àì-lè bá obìnrin láṣepọ̀, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógúnjilelogun pokùnso sínú oko bàbá rẹ̀ ní Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, October 30, 2021

Nítorí àì-lè bá obìnrin láṣepọ̀, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógúnjilelogun pokùnso sínú oko bàbá rẹ̀ ní Kwara


Ọrọ buruku toun tẹrin nigba ti wọn sọ pe gendekunrin, ọmọọdun mejilelogun kan, Idris Shuaib gbẹmi ara rẹ, nitori iṣoro ai-le ba obinrin laṣepọ lasiko to ba wu.
 
AWIKONKO gbọ pe Ọjọbọ, Tọside niṣẹlẹ ọhun waye lagboole Ankara Wooro to wa lagbegbe Gwanara, nijọba ibilẹ Barutẹn, ipinlẹ Kwara.
 
Lara awọn to fiṣẹlẹ yii to wa leti jẹ ko ye wa pe kii ṣe akọkọ ree ti Idris yoo ti maa gbiyanju lati gba ẹmi ara rẹ lori iṣoro to ni yii, ṣugbọn ti wọn sọ pe ori lo n ko o yọ lọwọ iku ojiji.
 
Ọkan lara awọn ẹgbọn Idris to sọrọ sọ pe ṣe lo deede kuro nile laaarọn ọjọ naa, to si dagbere fun baba rẹ wi pe oun fẹẹ lọ sinu oko, iyẹn gẹgẹ bo ṣe maa n lọ, lai mọ pe o ni erongba buruku lọkan to fẹ lọ ṣe.
 
Awọn to n kọja lọ ninu oko la gbọ pe wọn ṣakiyesi kinni kan to n mu jolonjolo lori igi kaṣu bi aago ẹlẹpọn, igba ti wọn sunmọ ibẹ ni wọn rii pe Idris lo ti gbẹmi ara rẹ sibẹ.
 
Loju ẹsẹ ni wọn ti sare lọ fi to baba rẹ leti, ọrọ naa si di ohun apewaawo fun gbogbo awọn ara agbegbe ọhun.
 
Wọn n i latibẹ ni baba Idris, Mala Muhammad Idris ti gba ileeṣẹ awọn Sifu Difẹnsi lọ lati fi to wọn leti, ti wọn lawọn yẹn lo pada wa gbe oku naa lọ si mọṣuari fun ayẹwo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI