Awọn ololufẹ mi ni wọn sọ pe ki n jade du ipo agbẹnusọ PDP - Ṣẹgun Ṣowunmi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉWednesday, October 13, 2021

Awọn ololufẹ mi ni wọn sọ pe ki n jade du ipo agbẹnusọ PDP - Ṣẹgun Ṣowunmi


Agbẹnusọ fun Alaaji Atiku Abubakar to jade du ipo Aarẹ orilẹ-ede Naijiria lọdun 2019, Ọgbẹni Ṣẹgun Ṣowunmi, ẹni ti ọpọ awọn eeyan tun mọ si Sagbua ti sọ ọ di mimọ pe awọn ololufẹ oun ni wọn sọ pe koun jade lati du ipo akọwe ipolongo fẹgbẹ oṣelu alatako nni, Peoples Democratic Party, PDP.
 
O loun ko nii lọkan lati jade fun ipo naa, ṣugbọn awọn ti wọn nigbagbọ ninu oun, ni wọn n sọ pe koun jade lọ du ipo naa, to tun jẹ gẹgẹ bi agbẹnusọ fun ilọsiwaju ẹgbẹ PDP.
 
Ṣowunmi sọ pe "erongba gbogbo ọmọ ẹgbẹ kaakiri agbaye ni wi pe maa ṣe daadaa fun ẹgbẹ ni ilana yẹn, mo si ti n foju silẹ lati wo ibi ti wọn maa pada pin ipo naa si. O tiẹ ti foju han wi pe ilẹ Yoruba ni wọn pin in si.
 

"Eeyan ko gbọdọ sọ pe oun ko ṣe. Mo wa fẹẹ sọ fun un yin bayii, gẹgẹ bi ẹyin ti mo nigbagbọ ninu ẹ, mo n fẹ atilẹyin ati adura yin. Ọmọ Ogun ni wa, aṣoju ipinlẹ nla yii si ni wa, to si jẹ pe o ti di dandan ka sa gbogbo ipa wa lati ṣe iwọn ti a le ṣe, nibikibi ti wọn ba ti pe wa.
 
"Ọrọ nipa oṣelu temi jẹ fun idagbasoke ati ilọsiwaju orilẹ-ede Naijiria. Gbogbo yin ni mo dupẹ lọwọ ẹ."

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI