Dapọ Abiọdun ti dorí ìpínlẹ̀ Ògùn kodò - Adérìnókùn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, October 13, 2021

Dapọ Abiọdun ti dorí ìpínlẹ̀ Ògùn kodò - Adérìnókùn


Ọkan pataki lara awọn alẹnulọrọ ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Oloye Olumide Aderinokun ti sọ pe ijọba ti Ọmọọba Dapọ Abiọdun n ṣe gẹgẹ bi gomina ti dori ipinlẹ Ogun kodo, nitori pe ijọba gan-an ko ye e mọ.
 
Laipẹ yii ni Aderinokun sọrọ naa nibi ifọrọwerọ to ṣe nileeṣẹ redio kan nipinlẹ naa, to si ni ẹgbẹ oṣelu PDP ti n gbaradi lati gbajọba mọ ọn lọwọ lọdun 2023.
 
Aderinokun, ẹni to ti fi ajọ alaanu rẹ, Olumide and Stephanie Aderinokun Foundation ṣe iranlọwọ fawọn eeyan kaakiri agbaye, paapaa nipinlẹ Ogun sọ pe ipo ti ipinlẹ naa wa n kọ awọn araalu lominu, to si ni loun nigbagbọ pe suuru to lọjọ ni iṣakoso Gomina Abiọdun.

Ọkunrin naa, ẹni to tun jẹ Akinruyiwa tilu Owu tun sọ siwaju peipo to ṣeni laanu ni gbogbo awọn ọna nipinlẹ Ogun wa patapata, ti ko si si eyi to ṣee gba mọ fawọn mọto.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "Ebi ati iya ti pọ ju nilẹ yii, awọn eeyan ko ri ounjẹ jẹ mọ. Koda, awọn olukọ gan-an ti wọn gba lati ọdun kan le diẹ sẹyin ko le sọ fun mi pe nnkan ti wọn n koju tẹ wọn lọrun.
 
"Mo wa nilu Ifọ ati Ewekoro lọjọ meloo kan sẹyin, mo si ri ipo tawọn opopona nibẹ wa, ibanujẹ nla lo jẹ nigba ti mo ri bi awọn opopona naa ṣe ri. Bi ijọba yii ba le sọ awọn nnkan ti wọn ti ṣe to dara, a jẹ pe a ṣẹṣẹ maa mọ bi a ṣe fẹẹ ṣagbeyẹwo ibi ti a n lọ.

"O tiẹ ti wa a ṣoro bayii lati sun, ka di oju mejeeji lakooko ti a wa yii. Radarada ni wọn n ṣe ijọba, ṣugbọn adura mi ni pe ki Ọlọrun tubọ jẹ ka wa ni iṣọkan laaarin oṣu mẹrindinlogun to ku ki wọn gbe baagi wọn."
 
Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ wi pe, lati le yọ awọn araalu kuro ninu iṣẹ ati oṣi, loun ṣe n ṣe iranlọwọ lọna toun mọ, nipa yiya awọn ọlọja lowo ti ko ni ele lori, toun n ṣe omi ẹrọ gidi fawọn eeyan, ati oniruuru iranlọwọ miran.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI