Wẹrẹ bayii ni aṣiri gbajugbaja pasitọ kan lorilẹ-ede Ghana tu si awọn ọmọ ijọ rẹ lọwọ nibi to ti n ko ibasun fun ọkan lara awọn arẹwa ijọ rẹ karakara ninu ṣọọṣi.
Ko si nnkan meji to n jẹ ki ọrọ pasitọ ti a ko tii mọ orukọ rẹ titi di asiko ti a ṣakojọpọ iroyin yii tan maa ya awọn eeyan lẹnu, bi ko ṣe pe ori pẹpẹ iwaasu lo ti n ba ọlọmọge naa laṣepọ karakara.
AWIKONKO gbọ pe ṣe ni awọn mejeeji naa n laagun bi ẹni to wọnu kọnga fun wakati mẹta, iyẹn nigba ti aṣiri wọn tu sita.
Ninu fidio ti awọn ti aṣiri naa tu si lọwọ fi ranṣẹ si AWIKONKO la ti rii pe oju ferese ni wọn ti kọkọ ri awọn mejeeji yii nibi ti wọn ti n gbe nnkan funra wọn lati ẹyin, to si n dun mọ wọn.
Igba ti awọn ti aṣiri naa tu si lọwọ rii pe ibasun naa ti wọ awọn mejeeji lara, lo mu ki wọn gba ẹnu ọna wọle, ti wọn si ri awọn mejeeji nihooho ọmọluabi.
Ki oloju to o ṣẹ ẹ, ero ti pe le wọn lori lati fi wọn ṣe ẹlẹya, iyẹn lọjọ Abamẹta tii ṣe Satide ana.
Iya ko to lilu fun awọn mejeeji nigba ti awọn eeyan pe le wọn lori, ti wọn si pada le wọn jade sita. Ṣugbọn ki wọn to o le wọn jade, awọn mejeeji ti bẹbẹ fun idariji ẹṣẹ wọn, ti wọn si ṣeleri wi pe awọn ko tun jẹ ṣe bẹẹ mọ.
AWIKONKO gbọ pe kii ṣe akọkọ ree ti pasitọ naa yoo maa ba awọn ọmọ ijọ rẹ laṣepọ, paapaa ninu ṣọọṣi ọhun, eyi ti wọn lawọn kan ti n fura si i.
Lara awọn to fura si wọn yii la gbọ pe wọn dọdẹ pasitọ naa. Igba ti wọn ri obinrin ti wọn jọ n ko ibasun funra wọn yii wi pe o de si ayika ṣọọṣi lawọn eeyan ti n tọpinpin ohun to fẹẹ ṣẹlẹ, ti wọn si lọ sapaọ si ẹyin ṣọọṣi.
Wọn ni bi wọn ṣe rii pe awọn mejeeji ti bọra sihooho ọmọluabi lati ba ara wọn laṣepọ ni wọn ti gbe foonu lati ya wọn, ko to di pe wọn pada lọ koju wọn.
No comments:
Post a Comment