Wọn kò jẹ́ kí Fouad Oki àtàwọn èèyàn ẹ̀ wọlé níbi ìbò APC tó wáyé nìpínlẹ̀ Èkó - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, October 17, 2021

Wọn kò jẹ́ kí Fouad Oki àtàwọn èèyàn ẹ̀ wọlé níbi ìbò APC tó wáyé nìpínlẹ̀ Èkó


Ọna mii in ni ibo lati yan awon oloye ẹgbẹ tuntun nipinlẹ Eko yọri si lana an ọjọ Abamẹta, nigba ti wọn ko jẹ ki ọkan lara awọn oludije fun ipo alaga ẹgbẹ naa, Fouad Oki, raye wọle sibi ti eto naa ti waye.

AWIKONKO gbọ pe ko to to akoko naa ni oriṣiriṣi awuyewuye ti n waye ti ọkunrin naa si ti n pariwo lori ọna ti wọn gba ṣeto ibo ọhun lọna ti ko bojumu,to ni awọn alagbara kan lo fẹẹ ma lo agbara wọn ninu ẹgbẹ ọhun.

Eyi ni ko ṣe ya awọn eeyan lẹnu nigba ti wọn gbọ iwa ti wọn hu si ọkunrin yii atawọn eeyan ti wọn ni wọn gba fọọmu amọ ti wọn ko jẹ ki wọn ṣe ojuṣe wọn lọjọ aa lori bi wọn ṣe da wọn pada lati ẹnu abawọle ibi ti eto ọhun ti waye.

Titi di  akoko yii ọkunrin naa ko tii ba wa sọ nipa igbese tuntun toun atawọn eeyan ẹ fẹẹ gbe. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI