Bàbá arúgbó tó fipá já ìbálé ọmọ-ọmọ rẹ̀, ọmọ ọdún mẹ́fà ti há l'Òndó - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, October 15, 2021

Bàbá arúgbó tó fipá já ìbálé ọmọ-ọmọ rẹ̀, ọmọ ọdún mẹ́fà ti há l'Òndó


Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti tẹ baba arugbo ẹni ọdun merinlelọgọta kan, Ajayi Awẹ lori ẹsun wi pe o fipa ja ibale ọmọ ọdun mẹfa to jẹ ọmọ-ọmọ rẹ.
 
Agbegbe ti wọn pe B/98 Daja Ajowa-Akoko, to wa nijọba ibilẹ Ariwa Akoko, ipinlẹ Ondo niṣẹlẹ ọhun ti waye laipẹ yii.
 
Iya ọmọ naa, Arabinrin Fatimah Ọbademi, la gbọ pe o lọ fọrọ ọhun to ileeṣẹ ọlọpaa ẹkun Okeagbe-Akoko leti wi pe Ajayi fipa ja ibale ọmọ oun, ọmọ ọdun mẹfa, ti wọn si sare lọ gbe e.
 
Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, DSP Funmi Ọdunlami sọ pe Ajayi ti wa lọgba wọn, nibi ti wọn ti n fọrọ wa a lẹnu wo, ati pe awọn ti gbe ọmọ naa lọ si ọsibitu.
 
Ọdunlami sọ pe Ajayi yoo foju ba ile-ẹjọ lẹyin iwadii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI