Ilé iṣẹ́ ológun bẹ̀rẹ̀ ìgbaniwọlé, wọ́n kéde ọjọ́ tí fọ́ọ̀mù yóò dópin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, October 30, 2021

Ilé iṣẹ́ ológun bẹ̀rẹ̀ ìgbaniwọlé, wọ́n kéde ọjọ́ tí fọ́ọ̀mù yóò dópin


Ileeṣẹ ologun orilẹ ede Naijiria ti kede sita wi pe fọọmu igbaniwọle to kade lọjọ kẹwaa, oṣu kẹsan ọdun yii, yoo dopin lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kọkanla, ọdun yii.

Ori ikanni ayelujara la gbọ pe gbogbo awọn to nífẹẹ lati darapọ mọ iṣẹ ologun yoo ti gba fọọmu naa lai laaguna jinna, nibẹ si ni wọn yoo ti forukọsilẹ.

Ninu atẹjade ti akọwe agba nileeṣẹ Bureau of Cabinet and Special Service, Ọgbẹni Ọlanrewaju Saka fi sita lo ti jẹ ko di mimọ pe ọfẹ ni fọọmu naa lori ikanni ayelujara ti https://recruitment.army.mil.ng.

O tẹsiwaju pe ori ikanni naa ni wọn yoo ti mu awọn ti ṣe ayẹwo fun gbogbo awọn to ba forukọsilẹ patapata, lati mọ awọn to yege ninu wọn, ko to di pe wọn kan si wọn lati wa ṣe idanrawo.

Bẹẹ lo sọ pe awọn to ba fẹẹ gba fọọmu naa gbọdọ jẹ ọdọ ti wọn ko tii fẹ iyawo tabi ni ọkọ, ti wọn si gbọdọ jẹ ọmọ Naijiria, ti wọn si gbọdọ ni nọmba idanimọ ijọba apapọ ti a mọ si National Identify Number (NIN) ati nọmbda idanimọ banki, iyẹn Bank Verification Number (BVN).
 
AWIKONKO gbọ pe awọn iwe ẹri bii WASSCE, GCE, NECO, NABTEB, ati City and Guild Certificate lawọn to ba fẹẹ gba fọọmu naa gbọdọ ni, gẹgẹ bi ohun amuyẹ, ati pe wọn ko gbọdọ ju ọdun mejidinlogun si mejilelogun ni wọn gbọdọ jẹ.
 
Wọn tun fi kun un pe ọjọ kọkanlelọgbọ, oṣu kin-in-ni, ọdun 2022 ni idanrawo yoo bẹrẹ ni pẹrẹu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI