Ìyá àtọmọ gún màmá arúgbó nígò pa l'Ógùn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, October 30, 2021

Ìyá àtọmọ gún màmá arúgbó nígò pa l'Ógùn


Afi bi ẹfun lọrọ ri nigba iya ati ọmọ rẹ gun mama arugbo, ẹni ọgọta ọdun kan pa nilu Ojodu, ijọba ibilẹ Ifọ, ipinlẹ Ogun lọsẹ to kọja yii.
 
Iyabọ Ọlashẹyinde lorukọ iya arugbo ti a gbọ pe Gowin Ogbeifu, ọmọ ọdun mẹtadinlogun ati mama rẹ, Mary Ogbeifu, ẹni ọdun marundinlogoji gun pa ladugbo Ọmọlara, Akoko Crescent to wa ni Yakoyo, Ojodu.
 
AWIKONKO gbọ pe ṣe ni Godwin, ti wọn pe ni odi ati aditi, nitori ti ko gbọrọ, bẹẹ si ni ko le sọrọ lọ sile mama naa, ṣugbọn ti wọn sọ pe maa naa lee danu.
 
Wọn ni kii ṣe akọkọ ree ti Godwin yoo maa lọ sile naa, ti wọn si ti kilọ fun un lọpọ igba wi pe ko yee wa sibẹ mọ. Bi wọn ṣe lee danu lo jẹ gba ile lọ, to si ṣalaye fun mama rẹ.
 
Pẹlu ibinu ni wọn so pe Maru fi tẹle lọ sibẹ lati lọ beere idi ti wọn fi le ọmọ rẹ danu, to si sọ ọrọ naa di ariwo nla mọ iya arugbo ọhun lọwọ.
 
Nibi ti wọn ti n fa ọrọ naa lọwọ la gbọ pe Godwin ti fa afọku igo to mu dani yọ, to fi gun Iyabọ ni ọrun. Wọn ni ṣe ni mama naa ṣubu lulẹ, to si bẹrẹ sii jẹ irora nla, ko to di pe o gbabẹ sọda sọrun alakeji.
 
Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn la gbọ pe wọn ko iya ati ọmọ naa lọ teṣan ọlọpaa nigba ti wọn ri nnkan to ṣẹlẹ yii.
 
Ni bayii, ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Bankọle ti paṣẹ pe ki wọn tare awọn mejeeji si ẹka ileeṣẹ wọn to n ṣe iwadii ọran lati tẹsiwaju iwadii, ki wọn si foju wọn ba ile-ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI