Lẹ́yìn ayẹyẹ ọjọ́-ìbí ẹ̀, àìsàn kídìnrín kọlu Ìgbòho lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ádùrá lọ̀rọ rẹ̀ nílò báyìí - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, October 13, 2021

Lẹ́yìn ayẹyẹ ọjọ́-ìbí ẹ̀, àìsàn kídìnrín kọlu Ìgbòho lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ádùrá lọ̀rọ rẹ̀ nílò báyìí


Ọkan lara awọn agbẹjọro fun Oloye Sunday Adeyẹmọ, tọpọ awọn eeyan mọ si Sunday Igboho lorilẹ-ede olominira Bẹnnẹ, Yọmi Alliyu ti gba gbogbo awọn ololufẹ ọkunrin naa lamọran lati dide adura fun un, ko ma ba a ku lojiji, nitori aisan kidinrin to lo kọluu.

Bakan naa ni Alliyu tun rawọ ẹbẹ si ijọba Bẹnnẹ lati foju aanu wo ọkunrin naa, nitori aisan kidinrin to kọluu mọnu ọgba ẹwọn to wa lati bi oṣu meji sẹyin.
 
Alliyu sọrọ yii lakooko to n ba akọroyin BBC Yoruba sọrọ, to si ni ọrọ ilera Igboho n fẹ amojuto oni kiakia, nitori pe ipo to wa bayii, ko yẹ fun iru ajijangbara bii tiẹ.

O sọ pe aisan to n ṣe Igboho kọja ohun ti wọn le maa fọọ bo, to si ni bo ṣe nilo abojumo naa lo tun nilo adura gidigidi.

Siwaju sii ni Alliyu sọ pe aisan naa bẹrẹ ni kete ti awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ digun lọ sile ẹ to wa ni Ṣoka nilu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ.

"Ko si aisan yii lara Sunday Igboho nigba ti wọn mu ni Kutọnu. O le debi wi pe ṣe ni wọn sare gbe e digbadigba ọ si ọsibitu. Mi o wa le sọ boya wọn ti gbe e pada sọgba ẹwọn, ṣugbọn ohun ti mo mọ ni pe o ni ipenija ilera, to si dabi ẹni pe aisan kidinrin ati ikọfun lo ni.

"Bo tilẹ jẹ pe mi o le sọ pato ẹya ara rẹ ti aisan naa tun ṣe akoba fun, ṣugbọn ṣa, mo mọ pe inu rẹ ni aisan to n ṣe e wa."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI