Ẹ jẹ́ kí àwọn àgùnbánirọ̀ lọ máa kojú àwọn Boko Haram - Fáyẹmí gba Buhari lámọ̀ràn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, October 13, 2021

Ẹ jẹ́ kí àwọn àgùnbánirọ̀ lọ máa kojú àwọn Boko Haram - Fáyẹmí gba Buhari lámọ̀ràn


Gomina Kayọde Fayẹmi tipinlẹ Ekiti ti gba Aarẹ Muhammadu Buhari lamọran lati jẹ ki awọn agunbanirọ lọ maa koju awọn Boko Haram ati agbesunmọmi, iyẹn awọn agbebọn to n da ilu ru kaakiri.
 
Fayẹmi sọ pe ṣe lo yẹ ki ijọba orilẹ-ede yii tun agbeyẹwo ofin awọn agunbanirọ naa ṣe, lati le jẹ ki wọn maa da wọn lẹkọọ nipa bi wọn ṣe le koju awọn Boko Haram ati agbebọn.
 
O ni ọna lati le tete gbogun ti iwa janduku, ipaniyan, igbebọn ni ki wọn maa yi awọn agunbanirọ si iṣẹ ologun, ki wọn ba a le gbogun ti Boko Haram, agbebọn, awọn to n ja fun iyapa, atawọn miran.
 
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "Pẹlu eyi, a le maa fi gbagede idanilẹkọọ wọn kọ awọn to ba finufẹdọ fun iṣẹ aabo lẹkọ lori ọrọ eto aabo lara ọtọ, eyi ti yoo ṣojuṣaara.

"Nipa eyi, owo ti wọn n fun awọn ileeṣẹ agunbanirọ, wọn yoo kan fi kun un ni, eyi ti yoo jẹ ki wọn fi ṣiṣẹ kun iṣẹ.

"Awọn ti wọn ko ba le darapọ mọ iṣẹ ologun le lọ sin ilẹ baba wọn lai gba owo kankan, iyẹn bi a ba fẹẹ fi eto agunbanirọ silẹ."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI