Awọn ọlọpaa ilẹ Amẹrika ti ṣawari oku ọmọ orilẹ-ede Naijiria, ọmọ ọdun mejilelogun kan, Faruq Osilalu, ninu mọto rẹ, lẹyin oṣu kan ti wọn ti n wa a.
Oṣu kẹsan to kọja la gbọ pe Faruq jade kuro nile, ti ko si pada sile mọ. Latigba naa la gbọ pe wọn ti n wa a, ti ko si sẹni to le sọ pato ibi to lọ.
Lẹyin ti iyawo rẹ, Alayna Singleton ko tete rii, lo ba gba teṣa ọlọpaa lọ lati fi to wọn leti, iyẹn lọjọ kẹtadinlọgbọn. Si iyalẹnu lẹyin ọjọ keji, a gbọ pe wọn kofiri mọto Faruq ni North Avenue to wa nilu Baltimore.
Iwadii kikun ti bẹrẹ lori iku to pa Faruq, paapaa bi iyawo rẹ ṣe sọ pe baba gidi to n toju oun ati ọmọ ti wọn bi loṣu kẹrin ọdun yii ni.
No comments:
Post a Comment