Wọ́n ti ju Dọlápọ̀ sẹ́wọ̀n oṣù mẹ́sàn-án l'Abẹ́òkúta o, ẹ̀sun jìbìtì ni wọ́n fi kàn án - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, October 31, 2021

Wọ́n ti ju Dọlápọ̀ sẹ́wọ̀n oṣù mẹ́sàn-án l'Abẹ́òkúta o, ẹ̀sun jìbìtì ni wọ́n fi kàn án


Ile-ẹjọ giga to wa nilu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun l'ogunjọ, oṣu yii ti ju gendekunrin kan, Musiliu Sọdiq Dọlapọ sẹwọn oṣu mẹsan-an pẹlu iṣẹ aṣekara lori ẹsun jibiti ori ayelujara ti a mọ si Yahoo-Yahoo ti ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajébanu lorilẹ-ede yii, iyẹn EFCC fi kan an.
 
Orukọ oyinbo ilẹ Amẹrika kan ti wọn pe ni Wilson Janet la gbọ pe Dọlapọ fi n lu awọn eeyan ni jibiti lori ikanni ayelujara ko to di pe aṣiri rẹ tu sita, ti ọwọ si tẹ ẹ.
 
AWIKONKO gbọ pe, yatọ si Musiliu ti wọn ju sẹwọn oṣu mẹsan-an yii, ile-ẹjọ naa tun ju Ọlawuyi Ọlanrewaju Ridwan sẹwọn oṣu mẹsan-an bakan naa lori ẹsun jibiti kan ṣoṣo yii.
 
Ẹsun ti wọn ka sawọn mejeeji lẹsẹ nile-ẹjọ giga ilu Abẹokuta ni pe wọn fi ọgbọn jibiti gbowo lọwọ oyinbo lori ayelujara, wọn pe ara wọn lohun ti wọn ko jẹ, eyi si lodi sofin to de ihuwasi ẹni lori ayelujara.
 
Nigba to n gbe idajọ kalẹ, Onidajọ Joyce Abdulmalik, paṣẹ pe kawọn ọmọde meji yii lọọ lo oṣu mẹsan-an mẹsan-an lẹwọn lai si aaye owo itanran, bẹẹ ni ki wọn da owo ti wọn fi jibiti gba naa pada.
 
Siwaju sii, ni ti Musiliu, owo to din ni irinwo dọla (340 USD) ni Adajọ paṣẹ pe o gbọdọ da pada sọdọ ẹni to lu ni jibiti ọhun, bẹẹ ni ko si da foonu iphone 11 pro max kan to wa lọwọ ẹ pẹlu Itel kan pada funjọba Naijiria.
 
O paṣẹ pe ki  Ọlawuyi da irinwo dọla (400USD) pada sapo ẹni toun naa lu ni jibiti. Bẹẹ naa ni yoo si tun da foonu iphone 11 to wa lọwọ tiẹ naa pada fun ijọba Naijiria, pẹlu ẹrọ gbohun-ghohun Bluetooth kan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI