Mákindé búra fáwọn kọmíṣánnà mẹwàá l'Ọyọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, October 11, 2021

Mákindé búra fáwọn kọmíṣánnà mẹwàá l'Ọyọ


Lonii, ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanla, oṣu kẹwaa ni Gomina Ṣeyi Makinde tipinlẹ Ọyọ bura fun awọn kọmiṣanna tuntun to ṣẹṣẹ yan sipo.

Nibi eto naa to waye nileeṣẹ ijọba to wa nilu Ibadan, ipinlẹ naa ni gomina ti gba wọn lamọran lati kọju mọ iṣẹ wọn, ki wọn si ṣiṣẹ takuntakun lati rii pe idagbasoke de ba ipinlẹ Ọyọ.

Awọn kọmiṣanna mẹwaa ti Gomina Makinde bura fun naa ni: Ọmọwe Wasiu Ọlatunbọsun, kọmiṣanna f'ọrọ iroyin, aṣa ati irin ajo afẹ; Adeniyi Adebisi, kọmiṣanna f'ọrọ iṣẹ agbẹ ati idagbasoke igberiko; Amofin Rahman Abiọdun Abdul-Raheem, kọmiṣanna f'ọrọ eto ẹkọ; Amofin Ọlasunkanmi Ọlalẹyẹ, kọmiṣanna f'ọrọ eto okoowo, ileeṣẹ ati ẹgbẹ alajẹṣẹku.

Awọn miran ni: Ṣeun Fakorede, kọmiṣanna f'ọrọ ọdọ ati ere idaraya; Alaaja Kafilat Ọmọlabakẹ Ọlayiwọla, kọmiṣanna f'ọrọ awọn obinrin; Abiọdun Oni, kọmiṣanna f'ọrọ eto ayika ati ohun alumọni; Ọjọgbọn Musibau Babatunde, kọmiṣanna f'ọrọ eto iṣuna ati alagbekalẹ eto ọrọ aje; Ṣẹgun Ọlayiwọla, kọmiṣanna f'ọrọ ilẹ ati ilegbee ati Ọmọwe Bọde Ladipọ toun jẹ kọmiṣanna f'ọrọ eto ilera.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI