Nítorí owó olówó, àwọn tọ́ọ̀gì páàyàn méjì n'Íbàdàn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉMonday, October 11, 2021

Nítorí owó olówó, àwọn tọ́ọ̀gì páàyàn méjì n'Íbàdàn


Ko din ni eeyan meji ti a gbọ pe awọn tọọgi lu pa lopin ọsẹ to ṣẹṣẹ pari yii, nigba ti wọn sọ pe owo ti ọsibitu kan gbe silẹ fawọn tọọgi yii lo dija wọn silẹ, lakooko ti wọn n pin in lọwọ.
 
Michael Akinwale ati Isiaka Sooku lawọn meji ti a gbọ pe wọn lu pa lagbegbe Ọja Igbo to wa nilu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ.
 
A gbọ pe ọsibitu kan to wa lagbegbe naa lo ṣe omi ẹrọ fawọn ara agbegbe yii, ti wọn si lawọn tọọgi to wa nitosi n beere owo lọwọ wọn, eyi lo jẹ ki awọn alakoso ọsibitu naa gbe owo kalẹ fun wọn lati lọ pin in.
 
Nibi ti wọn ti n pin owo ọhun lọwọ la gbọ pe lara awọn ti ko tẹ lọrun ti sọ ọ dija igboro, ti ọrọ si di boolọ o yago lọna.
 
Asiko ti wọn n fa ọrọ owo yii lọwọ ni wọn lawọn meji ti dagbere faye, ti awọn yooku si na papa bora. Fun bii wakati mẹta la gbọ pe gbogbo agbegbe naa fi pa lọlọ.

Itẹkuu kan to wa lagbegbe Akanran nilu Ibadan la gbọ pe wọn sin awọn mejeeji naa si.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI