Níbi tí Bọ́lánlé ti lọ jalè lọwọ́ tí tẹ̀ ẹ́ n'Íjẹ̀bú - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, October 4, 2021

Níbi tí Bọ́lánlé ti lọ jalè lọwọ́ tí tẹ̀ ẹ́ n'Íjẹ̀bú


Ọrọ ti Jesu Olugbala sọ gbẹyin lori igi agbelebu wi pe 'O pari', ni wọn lo jade lẹnu gendekunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Bọlanle Ojomu, ẹni ti ọwọ tẹ lakooko to lọ jale ladugbon Silver Estate, Odomalasa to wa nilu Ilese Ijẹbu, ipinlẹ Ogun.

Ibi ti wọn sọ pe Bọlanle ti lọ digunjale pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ lọwọ ti tẹ oun nikan ni nnkan bi aago mejila aabọ, ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to ṣẹṣẹ kọja yii.
 
Wọn nibi ti Bọlanle atawọn ẹmẹwa rẹ ti n jale lọwọ lawọn ara agbegbe naa ti ranṣẹ ọlọpaa Ilese Ijẹbu fun aabo. Ki awọn ọlọpaa si too de, ọwọ ti ba Bọlanle pẹlu ibọn ilewọ kekere kan ti wọn gba lọwọ ẹ.
 
A gbọ pe igbiyanju awọn eeyan atawọn ọlọpaa lati ri awọn yooku mu ja si pabo.
 
Adele kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun Abiọdun Alamutu nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ sọ pe oun ti paṣẹ ki iwadii tubọ bẹrẹ lati rii pe ọwọ tẹ awọn yooku to salọ naa, lati le fi wọn jofin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI