Ó mà ṣe o! Èèyàn mẹ́rin gan mọ́ná nínú ṣọ́ọ̀ṣì l'Ékòó, ìsìn ìdúpẹ́ ni wọ́n fẹ́ẹ́ ṣe - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉMonday, October 4, 2021

Ó mà ṣe o! Èèyàn mẹ́rin gan mọ́ná nínú ṣọ́ọ̀ṣì l'Ékòó, ìsìn ìdúpẹ́ ni wọ́n fẹ́ẹ́ ṣe


Ko din ni eeyan mẹrin ti wọn jade laye lọjọ Aiku, Sannde ana ninu ṣọọṣi Aladura kan ti wọn pe ni El-Adonai Evangelical Ministry (Aladura), eyi to wa ladugbo Jibowu, Abule-Ẹgba nipinlẹ Eko, nigba ti wọn sọ pe ṣe ni wọn gan mọ ina mọnamọna.
 
Eeyan mẹfa la gbọ pe wọn fara kaaṣa nibi iṣẹlẹ ọhun, ṣugbọn ti AWIKONKO gbọ pe awọn mẹrin lo pada ba iṣẹlẹ naa lọ, ti awọn meji yooku ṣi n gba itóju lọwọ titi di asiko taa pari akojọpọ iroyin yii.
 
Nnkan bi aago mẹjọ ku iṣẹju mẹrindinlọgbọn la gbọ pe iṣẹlẹ naa waye, nigba ti wọn sọ pe asiko ti awọn ọmọ naa n gbiyanju lati paarọ asia ṣọọṣi naa ni irin rẹ kọ waya ina, to si mu ki ina gbe wọn.
 
Eto ayẹyẹ isin idupẹ la gbọ pe wọn fẹẹ ṣe ninu ṣọọṣi naa, ko to di pe ijamba doju isin naa ru. Agbalagba meji ati ọmọ kekere meji ni wọn ba iṣẹlẹ naa lọ, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
 
Jamiu, ọkan lara awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe inu ṣọọṣi naa lawọn wa nigba ti iṣẹlẹ naa waye, to si lọ jẹ iyalẹnu fawọn nigba tawọn ri oku awọn mẹrin nilẹ.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI