Nítorí àrùn 'HIV/AIDS' tó kó lára ìyàwó rẹ̀, Pasitọ George lu ìyàwó ẹ pa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, October 11, 2021

Nítorí àrùn 'HIV/AIDS' tó kó lára ìyàwó rẹ̀, Pasitọ George lu ìyàwó ẹ pa

 
'Iru kileyi' lariwo to n ti ẹnu awọn ara agbegbe Nyamira County, to wa lorilẹ-ede Kenya mu sẹnu lọsẹ to kọja yii, nigba ti wọn gbọ pe gbajugbaja pasitọ kan, Pasitọ George Abisa pa iyawo rẹ danu, toun naa si tun pa ara rẹ pẹlu.
 
AWIKONKO gbọ pe oloṣelu kan ti wọn n lu du ipo Bogichora MCA ni wọn sọ pe iyawo Pasito Abisa n tẹle jade ni nnkan bi oṣu meloo kan sẹyin, ti wọn si sọ pe iwọlewọde wọn mu ifura dani wi pe wọn n yan ara wọn lale.
 
Lara awọn to fiṣẹlẹ yii to AWIKONKO leti sọ pe irọlẹ ọjọ Iṣẹgun, ọjọ karun-un, oṣu yii ni Abisa pa iyawo rẹ, toun naa si pokun so sinu ile.
 
Ṣaaju, ki Abisa too pa iyawo rẹ, wọn lo beere idi pataki to fi n yan oloṣelu naa lale, ati idi to fi lọ ko arun kogboogun ti HIV/AIDS wa sile foun, ṣugbọn ti wọn ni ẹbẹ ni obinrin ọhun n bẹ fun idariji.
 
Pẹlu ibinu ni Abisa fi lọ fa ọbẹ yọ, to si gun iyawo rẹ titi to fi dakẹ mọ-ọn lọwọ.
 
Bo ṣe rii pe obinrin naa ti dakẹ, loun naa ba sare lọ mu iwe, to si kọ ọ sibẹ nipa idi to fi pa iyawo rẹ. Ninu lẹta naa lo ti fẹsun kan iyawo rẹ wi pe o yan oun jẹ, ati pe o tun jẹ koun ko arun kogboogun lara rẹ lai jẹ koun mọ.
 
O loun ko le laju silẹ lati maa gbe arun kaakiri igboro, lo jẹ koun tete ṣe idajọ lọwọ ara oun. Bo si ṣe kọ iwe naa tan, lo ba pokunso, to si gba ẹmi ara rẹ.
 
Nigba ti wọn lawọn araadugbo ko tete ri wọn lati jade, lo mu ki wọn lọ ranṣẹ sawọn ọlọpaa lati wa mọ ohun to n ṣẹlẹ, to si jẹ pe oku tọkọ tiyawo naa ni wọn ba ninu ile nigba ti wọn ja ilẹkun wọle.
 
Lẹta naa to tẹ AWIKONKO lọwọ ree:






No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI