Múkáílà, ọmọ ogún ọdún tó jí ọ̀kadà gbé n'Ilé-Ifẹ̀ ti fojú ba ilé-ẹjọ́ o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, October 11, 2021

Múkáílà, ọmọ ogún ọdún tó jí ọ̀kadà gbé n'Ilé-Ifẹ̀ ti fojú ba ilé-ẹjọ́ o


Bo tilẹ jẹ pe Rasaq Mukaila, ọmọ ogun ọdun ti wọn lo ji ọkada gbe lagbegbe Alabata to wa labule Ifẹgbemi nitosi Ile-Ifẹ lọjọ kẹrin, oṣu yii ti foju ba ile-ẹjọ, sibẹ, afaimọ ni ko ma pada fi ẹwọn gbara.
 
Ẹsun meji ọtọọtọ to nii ṣe pẹlu dida alaafia ilu laamu ati ole jija ni wọn fi kan Mukaila, ẹni ti wọn sọ pe nnkan bi aago mẹta ọsan ọjọ naa lo ji ọkada Bajaj ti nọmba idanimọ rẹ jẹ FFE 194 QF gbe. Wọn lowo ọkada naa, to jẹ ti Abiọdun Ọdẹyẹmi ko din ni ẹgbẹrun marundinlọọdunrun {N295,000} naira.
 
AWIKONKO rii gbọ pe wọn ni ṣe ni Mukaila tun da wahala ati ariwo nla silẹ, lakooko to fẹẹ ji ọkada naa gbe, eyi to jẹ kọwọ awọn eeyan tẹ ẹ, ti wọn si fa a le awọn ọlọpaa lọwọ.
 
Agbẹjọro Mukaila, Okoh Wonder rawọ ẹbẹ si ile-ẹjọ lati faaye silẹ fun beeli, ko si lanfaani lati maa gba ile wa, bẹẹ lo ṣeleri wi pe Mukaila ko nii salọ tii igbẹjọ naa yoo fi pari.
 
Nigba to n gbe idajọ kalẹ, Onidajọ Oluwatosin Adediwura sọ pe ki wọn gba beeli Mukaila pẹlu ẹgbẹun lọna ọọdunrun naira ati oniduro meji, to ba n san owo ori rẹ deedee, paapaa to tun ni iwe ẹri owo ori ọdun mẹta gbako, to si sun igbẹjọ miran siwaju si ọjọ ki-in-ni, oṣu kejila, ọdun yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI