Ọjọ́ mọ́kànlélógójì lẹ́yin ikú ìyá Tóyìn, gbajúmọ̀ akọ̀ròyìn l'Ékòó - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉSaturday, October 9, 2021

Ọjọ́ mọ́kànlélógójì lẹ́yin ikú ìyá Tóyìn, gbajúmọ̀ akọ̀ròyìn l'Ékòó


Oni, ọjọ kẹsan, oṣu kẹwaa lo pe ọjọ mọkanlelogoji gbako ti mama gbajugbaja akọroyin nni to filu Eko ṣe ibugbe, Toyin Agbọlade, iyẹn Diakoni Felicia Agbọlade jade laye lẹni ọdun mọkanlelọgọta.
 
Gẹgẹ bi AWIKONKO ṣe gbọ, ọgbọn ọjọ, oṣu kẹjọ, ọdun yii ni Diakoni Felicia Agbọlade jade laye, to si jẹ pe ọjọ naa gan-an ni wọn fi eeru fun eeru, erupẹ fun erupẹ.
 
Ẹsẹ ko gbero lọjọ ti wọn sinku mama naa nilu Eko, nitori ti wọn sọ pe ojiṣẹ Ọlọrun gidi ni ninu ijọ to n lọ.
 
Nigba to n b'AWIKONKO sọrọ lonii, Toyin to jẹ akọroyin ati olootu nileeṣẹ Akede Oodua to n gbe iwe iroyin Alariya Oodua sọ pe bi ala lọrọ iku mama naa ṣi n jẹ foun, nitori pe abiyamọ tootọ ti kii fọrọ ọmọ ṣere ni.
 
Toyin sọ pe bo tilẹ jẹ pe mama naa ti lọ, sibẹ awọn tun n dupẹ lọwọ Ọlọrun wi pe ko fi wọn silẹ, to si n pese fun aini wọn latigba naa.

Diẹ ree lara bi wọn ṣe sinku mama Toyin, ati bi eto ọjọ mẹjọ ṣe waye nigba naa:
No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI