Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ gomina wọn, AbdulRahman AbdulRazaq ti da ọga agba nile ẹkọ Keu Madrasah duro lori aṣemaṣe ti wọn ṣe ninu fọnran kan to gun ori ikanni ayelujara laipẹ yii.
Fọnran naa, eyi to tẹ AWIKONKO lọwọ lopin ọsẹ ti a ṣẹṣẹ lo tan yii, iyẹn ọjọ Abamẹta, Satide ana la ti ri awọn akẹkọọ mẹrin kan, ti wọn da igi jọ lati lu awọn akẹkọọ ẹgbẹ wọn.
Lonii ni ijọba Kwara gbe igbimọ dide lati ṣabẹwo si ile-ẹkọ Keu naa, nibi ti wọn ti lọ ṣe iwadii kikun nipa idi ti wọn fi lu awọn akẹkọọ naa to bẹẹ.
Awọn to lọ sibẹ ni kọmiṣanna fọrọ eto ẹkọ, Hajia Sa'adatu Modibbo Kawu; Oludamọran pataki fun gomina lori ọrọ ẹin Isilaamu, Alaaji Danmaigoro; Ọmọwe Saudat AbduBaqi ti fasiti Ilọrin; Malaamu Lawal Ọlọhungbẹbẹ ti fasiti ipinlẹ Kwara ati akọwe iroyin gomina, Rafiu Ajakaye.
Yatọ si awọn wọnyi, ọga ọlọpaa ẹkun Ganmo tiṣẹlẹ ọhun ti waye, Oko Nkama ati aṣoju ileeṣẹ Sifu Difẹnsi, Parati AbdulHameed ni wọn jọ kọwọ rin lọ.
Nibẹ ni wọn ti farabalẹ gbọ ohun to ṣẹlẹ, ti onikaluku si sọ nnkan to ri.
Fọnran naa ree:
No comments:
Post a Comment