Ojúṣe gbogbo wa lọ̀rọ̀ ètò ààbò jẹ́ ní Nàìjíríà - AbdulRazaq pariwo síta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, October 1, 2021

Ojúṣe gbogbo wa lọ̀rọ̀ ètò ààbò jẹ́ ní Nàìjíríà - AbdulRazaq pariwo síta


L'Ọjọbọ, Tọside ana, ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq gba awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria lamọran lati mura giri sọrọ eto aabo, ati pe ki wọn wa ni ojulalakan-fi-n-ṣọri lati rii pe eto aabo dohun igbagbe patapata lawujọ wa.

Gomina AbdulRazaq lo parọwa yii nibi ayẹyẹ eto ikẹkọọjade awọn akẹkọọ ile-ẹkọ eto ilera ti Nigerian Navy College of Health Sciences (NNCHS), to wa nilu Ọffa, ipinlẹ Kwara.
 
Ọgbẹni Kayọde Alabi, igbakeji gomina to ṣoju ọga rẹ lakooko to n sọrọ jẹ ko di mimọ pe ojuṣe gbogbo araalu ni ọrọ eto aabo jẹ, paapaa lakooko ipenija ti a wa lorilẹ-ede yii.
 
Nibẹ lo tun ti jẹ ko di mimọ pe nigba ti ijọba n ṣe ojuṣe wọn lati rii pe ọrọ eto aabo kẹsẹjari, nipa pipese awọn nnkan to le mu irọrun ba iṣẹ eto aabo, sibẹ, awọn araalu naa gbọdọ wa ni ojufo.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe:
"Ẹ ma ṣe gbagbe lati maa ta awọn ileeṣẹ eleto aabo, awọn olori agbegbe atawọn tọrọ ba kan lolobo, nigba ti ẹ ba ri ohun ajoji tabi eeyan ti ẹ ko mọ lagbegbe yin. Bi ẹ ba ri ohunkohun, ẹ sọrọ sita lakooko to yẹ. Nipa eyi, a le daabo bo orilẹ-ede ati agbegbe wa."
 


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI