Kò si ẹ̀tànjẹ wí pé Nàìjíríà n kojú àsìkò ìpèníjà tó n sàkóbá fún ìdàgbàsókè àpapọ̀ - AbdulRazaq sojú abẹ níkòó - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, October 1, 2021

Kò si ẹ̀tànjẹ wí pé Nàìjíríà n kojú àsìkò ìpèníjà tó n sàkóbá fún ìdàgbàsókè àpapọ̀ - AbdulRazaq sojú abẹ níkòó


Bi gbogbo ọmọ orilẹ-ede Naijiria jakejado ṣe n ṣajọyọ ayajọ ọjọ ominira kaakiri agbaye, ti onikaluku si n sọ oriṣiriṣi nipa Naijiria, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti sọ pe ko si ariyanjiyan ninu wi pe orilẹ-ede yii n la akooko ipenija kọja.
 
Ninu ọrọ rẹ to fi n ki gbogbo ọmọ orilẹ-ede yii ku ajọyọ ọdun mọkanlelọgọta ominira to n waye lonii, ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹwaa, ọdun 2021 lo sọrọ naa jade, to si ni akooko ipenija naa ko ni pẹẹ dopin.
 
"Mo darapọ mọ Aarẹ ati awọn ọmọ orilẹ-ede yii lati gbe oṣuba kare fawọn akọni wa, paapaa awọn ọmọ ipinlẹ Kwara lọjọ ayajọ ọdun mọkanlelọgọta ominira ti a n ṣe yii.
 
"Ko si ẹtanjẹ kankan wi pe orilẹ-ede wa n koju akooko ipenija otitọ ninu idagbasoke apapọ. Sibẹ, mo ni igbagbọ wi pe a maa bori, a si maa dide pada pẹlu okun ati agbara, ti a si tun maa wa ni iṣọkan pẹlu aṣeyọri nla gẹgẹ eeyan kan ṣoṣo.

"A le ma si nibi to yẹ ka wa, ṣugbọn sibẹ, orilẹ-ede wa ko duro loju kan, bẹẹ ni a ṣi tun ni ireti. Nipa iṣọkan, akikanju, ikora-ẹni-nijanu, ireti, aniyan ohun rere, ati igbagbọ ninu okun ti a ni ninu gbigbooro wa nipa ifẹ, a maa leke, ti a si maa de ebute ogo gẹgẹ bi orilẹ-ede to tobi julọ nilẹ adulawọ lagbaye."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI