Ọmọniyì lu bàba arúgbó tí wọ́n jọ n fẹ́ obìnrin kan ṣoṣo pa l'Owódé Yewa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, October 17, 2021

Ọmọniyì lu bàba arúgbó tí wọ́n jọ n fẹ́ obìnrin kan ṣoṣo pa l'Owódé Yewa


Kani kii ṣe pe awọn eeyan tete debẹ ni, o ṣee ṣe ki Bisi Ọmọniyi ti wọn lo ṣa baba agbalagba ti wọn jọ n fẹ obinrin kan naa nilu Ajilete, ijọba ibilẹ Owode Yewa pa lọsẹ to kọja yii ti na papa bora, ṣugbọn ti wọn ko jẹ ko raaye salọ.
 
Ọmọniyi, ọmọ ọdun marundinlọgbọn la gbọ pe o ṣa baba agbalagba, ẹni aadọta ọdun naa, Akinyẹmi Wahab Alani lada pa.
 
Gẹgẹ bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ ṣe sọ, wọn ni ṣe ni Ọmọniyi lọ sile obinrin naa, Kafayat Ṣakariyau, pẹlu erongba lati sun nibẹ mojumọ, ko si le raaye ko ibasun fun un.
 
Igba ti wọn lo debẹ lo jẹ iyalẹnu fun un wi pe Alani ti wa ninu yara obinrin naa, toun naa si fẹẹ sun mọjumọ sibẹ.
 
Wọn ni gbogbo bo ṣe kan ilẹkun wi pe oun fẹẹ wọnu ile, ni Kafayat n sọ pe ko saaye, nitori pe oun ni alejo, ati pe ko jẹ kawọn fi ipade si ọjọ miran.
 
Pẹlu ibinu la gbọ pe Ọmọniyi fi ja ilẹkun wọle, to si ba baba naa lori bẹẹdi pẹlu iro nidii. Wọn ni bo ṣe ri eyi lo ti wọnu yara lọ, to si fa ada yọ, eyi to fi ṣa baba naa pa.
 
Ariwo ti wọn ni Kafayat n pa wi pe kawọn eeyan gba oun lo mu kawọn to wa nitosi sare debẹ lati mọ ohun to n ṣẹlẹ, to si jẹ kayeefi nigba ti wọn ba Alani ninu agbara ẹjẹ.
 
Gbogbo akitiyan lati doola ẹmi Alani lo ja si pabo, nitori nigba ti wọn gbe e de ọsibitu fun itọju, awọn dokita sọ pe oku ni wọn gbe wa fawọn, ti wọn si gbabẹ gbe e wọ mọṣuari loju ẹsẹ.
 
Wọn ni bi Ọmọniyi ṣe ri ohun to ṣẹlẹ yii lo ti gbiyanju lati na papa bora, ṣugbọn ti awọn eeyan ko jẹ ko raaye juba ehoro. Latibẹ ni wọn ti lọ fa a le awọn ọlọpaa Owode Ẹgbado lọwọ.
 
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun to fi iroyin naa to wa leti lo jẹ ka mọ pe agbegbe kan ti wọn n pe ni Ibasa to wa nilu Oke-Ọdan ni Ọmọniyi ti wa a ba Kafayat l'Ajilete, to si jẹ pe pẹlu ibinu lo fi ṣa Alani, ẹni tọpọ awọn eeyan tun mọ si Ajiọlọpọn pa.
 
 Ni bayii, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Bankọle, ti paṣẹ pe ki ileeṣẹ wọn to n ri sọrọ ipaniyan, iyẹn SCIID gba iṣẹ iwadii naa ṣe, ko to di pe wọn foju Ọmọniyi ba ile-ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI