Àwọn ọmọ 'Yahoo' méjìlá dèrò àtìmọ̀lé n'Íbàdàn - IROYIN AWIKONKO

YÀJÓ-YÀJÓ
Sunday, October 17, 2021

Àwọn ọmọ 'Yahoo' méjìlá dèrò àtìmọ̀lé n'Íbàdàn


Ko din ni awọn afurasi ọmọ 'Yahoo' mejila tọwọ awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ to n gbogun ti ṣiṣe owo kumọkumọ ati iwa jibiti lorilẹ-ede yii, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), ẹka tilu Ibadan tẹ l'ọjọ Ẹti, Furaide to kọja yii.
 
Agbegbe Alapata ati Awotan to wa nilu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ lọwọ ti tẹ awọn mejila naa, gẹgẹ bi Wilson Uwujaren to jẹ agbẹnusọ fawọn EFCC ṣe ṣalaye fawọn akọroyin.
 
Uwujaren sọ pe pupọ wọn ni wọn ṣi wa nile-ẹkọ, ti wọn n kẹkọọ lọwọ.
 
Oriṣiriṣi awọn ẹru ofin to ṣakoba fun wọn ni wọn gba lọwọ wọn nigba ti aṣiri wọn tu.
 
A gbọ pe mọto Toyota Corolla, foonu olowo nla ati ẹrọ kọmuputa alagbeka loriṣiriṣi ni wọn gba lọwọ wọn.
 
EFCC ti wa jẹ ko di mimọ pe awọn eeyan naa ko ni pẹ ẹ foju ba ile-ẹjọ.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI