Òpin débá ayé fàmílétè-ki-n-tutọ́ tàwọn òdaràn ń jẹ ní Kogí - Yahaya Bello fọwọ́ sọ̀yà - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, October 4, 2021

Òpin débá ayé fàmílétè-ki-n-tutọ́ tàwọn òdaràn ń jẹ ní Kogí - Yahaya Bello fọwọ́ sọ̀yà


Gomina ipinlẹ Kogi, Alaaji Yahaya Adoza Bello ti ṣeleri wi pe opin ti deba gbogbo awọn ọdaran to fi ipinlẹ naa ṣe ibugbe, paapaa awọn ọdaran to n jaye familete-ki-n-tutọ, nitori pe gbogbo wọn ni omi yoo dilẹ lẹyin asunṣujẹ wọn laipẹ.
 
O ni gbogbo ile tawọn ba ṣawari wi pe awọn ọdaran n lo lati sapamọ si fi ṣiṣẹ ibi loun yoo wo lulẹ danu lai ṣẹku ẹyọkan ṣoṣo.
 
Lonii, ọjọ Aje., Mọnde ni Gomina Bello sọrọ naa jade nibi eto kan ti ileeṣẹ ologun orilẹ-ede yii, ẹka tipinlẹ naa ṣe nipa alaafia, iyẹn Exercise Enduring Peace, to waye nikorita Zariagi ati Kabba, ijọba ibilẹ Adavi, ipinlẹ naa.
 
Bello, sọ pe ijọba oun ko ni fi ohunkohun silẹ lati pa gbogbo ibugbe awọn ọdaran run patapata nipinlẹ naa, to si gbe oṣuba kare fun ọga ologun, Lt. Gen. Farouk Yahaya, lori akitiyan rẹ lati gbogun ti awọn ọdaran lorilẹ-ede yii.
 
Bakan naa lo tun fi idunnu rẹ han lori ajọṣepọ to dan mọnran laaarin awọn eleto aabo kaakiri ipinlẹ Kogi nipa titẹri awọn ọdaran ati agbebọn ba.
 
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe:
 
"Iṣakoso mi ko nii da ọdaran kankan si nipinlẹ Kogi. A ma maa tẹsiwaju lati wo ile wọn lulẹ, mi o fẹẹ mọ bi wọn ṣe sunmọ awọn eeyan to. Kogi jẹ ile alaafia, ati pe ijọba mi ti ṣeleri lati rii pe awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ yii sun oorun asundọkan, nipa didi oju mejeeji."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI