Nítorí iṣẹ́ abẹ tí Ọ̀ṣọbà ṣe, ẹ gbọ́ ohun tí Gómìnà Dàpọ̀ Abíódún sọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉMonday, October 4, 2021

Nítorí iṣẹ́ abẹ tí Ọ̀ṣọbà ṣe, ẹ gbọ́ ohun tí Gómìnà Dàpọ̀ Abíódún sọ


Gomina Dapọ Abiọdun tipinlẹ Ogun, ti ba gomina tẹlẹri nipinlẹ naa, Oloye Oluṣẹgun Ọsọba yọ lori aṣeyọri iṣẹ abẹ ti orunkun rẹ to lọ ṣe niluu Oyinbo lọsẹ to kọja yii.

Ọsibitu kan nilẹ Amẹrika ni Arẹmọ Ọṣọba ti ṣiṣẹ abẹ naa l'Ọjọbọ, Tọside, ọgbọn, ọjọ, oṣu kẹsan to kọja yii, ti iṣẹ abẹ naa si lọ gẹgẹ bo ṣe lai ni idaamu kankan ninu.
 
A gbọ pe lati bi ọdun meloo kan sẹyin ni orunkun ti n yọ Arẹmọ Ọṣọba lẹnu, eyi ti ko jẹ ko le duro tabi rin daadaa.
 
Nigba to n sọrọ ninu atẹjade ti akọwe iroyin rẹ, Ọgbẹni Kunle Ṣomọrin fi sita lọjọ Ẹti, Furaidee, Gomina Dapọ Abiọdun sọ pe inu oun dun wi pe baba naa ṣiṣẹ abẹ ọhun laṣeyọri, to si jẹ ko di mimọ pe ara rẹ ti n ya gidigidi.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI