Oríire nlá wọlé! Ẹgbẹ̀ta akẹ́kọ̀ọ́ jẹ́ anfààní ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ l'Ógùn, àjọ aláànú 'Olumide and Stephanie Adérìnókùn' ló gbé anfààní náà kalẹ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, October 20, 2021

Oríire nlá wọlé! Ẹgbẹ̀ta akẹ́kọ̀ọ́ jẹ́ anfààní ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ l'Ógùn, àjọ aláànú 'Olumide and Stephanie Adérìnókùn' ló gbé anfààní náà kalẹ̀


Omijẹ ayọ lo n bọ loju awọn obi kaakiri ipinlẹ Ogun lonii, Ọjọru, Wẹside, ogunjọ, oṣu kẹwaa, ọdun 2021 nigba ti ajọ ẹlẹyinju aanu kan ti wọn pe ni Olumide and Stephanie Aderinokun Foundation gbe eto ẹkọ ọfẹ kalẹ fawọn akẹkọọ ti ko din ni ẹgbẹta (600).

Gbọngan ayẹyẹ ti Ontec to wa ni Abiọla-Way nilu Abẹokuta, ipinlẹ naa ni eto ọhun ti waye, nibi ti awọn alaṣẹ ati awọn aṣoju ile-ẹkọ girama to wa kaakiri ijọba ibilẹ ogun to wa nipinlẹ Ogun ti peju pesẹ lati ṣajọyọ oriire nla naa.

Lara awọn to tun wa nibẹ ni Ọmọọba Lekan Tẹjuoṣo; Ọnarebu Waliu Taiwo; Ọnarebu Ṣoyẹmi Emmanuel Coker; Alaaji Sẹmiu Ṣhodipọ; Oloye Babatunde Ọdẹyẹmi to ṣoju alaga ẹgbẹ PCRC nipinlẹ Ogun; Oloye Bidemi Ọṣunbiyi; Ọnarebu Nikẹ ItsOkay; Ọnarebu Akinlabi Taiwo; Ọnarebu Biyi Akojede; Alaaja Tijani Zainab; Ọnarebu Yinusa Ọlajide; Ọnarebu Muyiwa Ọjẹbiyi atawọn miran.

AWIKONKO gbọ pe idanwo ni wọn kọkọ ṣe fun gbogbo awọn akopa, ko to di pe wọn mu awọn to peregede ninu wọn, eyi ti gbogbo wọn jẹ ẹgbẹta akẹkọọ.

Nibi eto naa lonii, ni wọn tun ti gba iwe ati oniruuru awọn ẹbun to ṣee lọ nile ẹkọ wọn. A gbọ pe eto ẹkọ ọfẹ naa ti owo rẹ ko din ni ẹgbẹrun lọna aadọta naira fun ẹni kọọkan wọn.

Nigba to n b'AWIKONKO sọrọ, Oloye Olumide Aderinokun dupẹ lọwọ Arabinrin Blessing Raymond to ronu lati gbe eto naa kalẹ, to si ni oun ko nii dawọ oore ṣiṣe duro laye.

Oloye Aderinokun sọ pe lara awọn ipinnu oun ni lati maa ṣe iranwọ fawọn eeyan, paapaa wi pe eto ẹkọ jẹ oun logun pupọ.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI