Ogbontarigi ọmọ 'Yahoo' méjì dèrò ẹ̀wọ̀n l'Abùjá - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, October 20, 2021

Ogbontarigi ọmọ 'Yahoo' méjì dèrò ẹ̀wọ̀n l'Abùjá


Ọjọ Aje, Mọnde, to kọja yii ni ile-ẹjọ giga tilu Abuja ju awọn gendekunrin meji kan ti wọn ko niṣẹ meji ju jibiti ori ayelujara lọ sẹwọn, lori ẹsun iwa jibiti ti wọn fi kan wọn.
 
Daniel Okoro ti inagijẹ rẹ n jẹ Michael Kani, ati James Nicholas, ni Onidajọ O. A. Musa ti ile-ẹjọ giga to wa ni Apo sọ pe ki wọn lọ fi ẹwọn oṣu mẹta ati meji gbara.
 
A gbọ pe Daniel n sọ lori ayelujara wi pe ọmọ ilẹ Amẹrika loun, ati pe ajọ iṣọkan agbaye, ti a mọ si United Nation loun n ba ṣiṣẹ papọ gẹgẹ bi oniṣegun oyinbo.
 
Wọn ni ẹtanjẹ yii lo fi lu Christiana Morgan, Auriel Correl ati ẹnikan ti wọn pe orukọ rẹ ni Phillip, gbogbon ni wọn sọ pe ọmọ ilẹ Amẹrika ni wọn, to si gba owo ti ko din ni miliọnu mẹwaa naira lọwọ wọn.
 
Ileeṣẹ EFCC to rọwọ to wọn, to si foju wọn ba ile-ẹjọ jẹ ko di mimọ pe lara owo ti Daniel lu jibiti rẹ lo fi ra mọto Lexus RX 350.
 
Ni ti Nicholas, ẹnikan ti wọn pe orukọ tirẹ ni Leongorman Simone Everett la gbọ pe oun lu ni jibiti miliọnu kan aabọ naira, lẹyin ẹtanjẹ wi pe oun le wọnu akanti ileeṣẹ yoowu, iyẹn hacker.
 
Awọn mejeeji ni wọn sọ pe awọn jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn lotitọ, ati pe awọn ko tun jẹ ṣe iru nnkan bẹẹ mọ laye, ṣugbọn ti agbẹjọro EFCC, E. G. Inalegwu ati Abel Adaji sọ pe ki ile-ẹjọ ma ṣe wo oju wọn rara, bi ko ṣe pe idajọ ododo lo ni lati waye lori wọn.
 
Onidajọ Musa wa paṣẹ pe ki Daniel lọ fi ẹwọn oṣu mẹta pere gbara, tabi ko san ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un gẹgẹ bi owo itanran; bẹẹ lo sọ paṣẹ pe ki Nicholas lo oṣu meji gbako tabi koun san ẹgbẹrun lọna aadọta naira gẹgẹ bi owo itanran.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI