Òṣèlú bẹ̀rẹ̀ l'Òndó, wọ́n rán àwọn agbanipa sí gbajúmọ̀ Ọnọrebu Afọlábí tó n ṣojú wọn l'Abùjá - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, October 19, 2021

Òṣèlú bẹ̀rẹ̀ l'Òndó, wọ́n rán àwọn agbanipa sí gbajúmọ̀ Ọnọrebu Afọlábí tó n ṣojú wọn l'Abùjá


Kani kii ṣe ori to ko gbajugbaja ọkan lara awọn ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin ipinlẹ Ondo nilu Abuja ni, iyẹn Ọnọrebu
Rasheed Ọlalekan Afọlabi yọ lọwọ iku ojiji ni, boya ki ba ti di ẹran ijẹ fawọn agbanipa l'ọjọ Aje, Mọnde ana.
 
Ọnọrebu Afọlabi to n ṣoju ẹkun Ifẹlodun/Boripe/Odo-Ọtin nilu Abuja la gbọ pe awọn agbanipa kọlu ikọ akọwọrin rẹ loju ọna Akurẹ si Okenne, ipinlẹ Kogi.
 
AWIKONKO gbọ pe Ọnọrebu Afọlabi ati iyawo rẹ, Arabinrin Abimbọla Afgọlabi ni wọn jọ wa kuro nile wọn to wa ni Ikirun laaarọ ọjọ Mọnde ana, ti wọn si n lọ si papakọ ofurufu tilu Akurẹ lati lọ wọ ọkọ baluu lọ silu Abuja, lai mọ pe awọn agbanipa n tẹle wọn lẹyin lati ṣiṣẹ ti wọn ran wọn.
 
Ipade gbogboogbo ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC to waye lopin ọsẹ to kọja yii la gbọ pe wọn wa fun.
 
A gbọ pe mọto meji rẹ, Ford SUV ati Ford Hilux lo gbe dani, ko to di pe wọn koju ẹ.
 
Lara awọn to fiṣẹlẹ naa to wa leti sọ pe ibi ti igbagbọ wa pe Ọnọrebu Afọlabi jokoo si ninu mọto mejeeji la gbọ pe awọn agbanipa naa doju ibọn wọn kọ.
 
Yatọ si eyi, awọn oniṣẹ ibi naa tun yinbọ lu gilaasi iwaju ati tẹyin, taya awọn mọto naa, lati le da wọn duro, ki wọn si le ri iṣẹ buruku wọn ṣe.
 
Wọn ni ọkan lara awọn akawọ ti wọn wa nibẹ lọjọ naa loun ti fura pe mọto Honda CRV kan ti n tẹle wọn lẹyin Ọṣun, iyẹn lati aarọ ọjọ naa, lai mọ pe o niṣẹ buruku kan to fẹẹ ṣe.
 
AWIKONKO gbọ pe wọn ko ri ọkunrin naa pa, ṣugbọn ti wọn ti fi iṣẹlẹ naa to ileeṣẹ ọlọpaa leti.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI