Ọtí àmupara ló jẹ́ kí n fipá já ìbálé ọmọ ọdún mẹ́tàlá l'Ékòó, mi ò mọ̀-ọ́n-mọ̀ - Sunday bẹ̀bẹ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, October 10, 2021

Ọtí àmupara ló jẹ́ kí n fipá já ìbálé ọmọ ọdún mẹ́tàlá l'Ékòó, mi ò mọ̀-ọ́n-mọ̀ - Sunday bẹ̀bẹ̀


Beeyan ba wa nibi ti baale ile, ẹni ọdun mejilelọgbọn kan, Sunday Ukeme ti n dọbalẹ rababa, wi pe ki wọn daṣọ aṣiri boun, ati pe iṣẹ eṣu ni boun ṣe fipa ja ibale ọmọ ọdun mẹtala kan ti a fi orukọ bo laṣiri, ko ni mọ igba ti yoo rẹrin takiti.
 
Ko si nnkan meji to jẹ ki ọrọ Ukeme maa jẹ iyalẹnu fawọn to wa nibẹ, bi ko ṣe ti bo ṣe n sọ pe ọti amupara toun mu, lo jẹ koun fipa ba ọmọ naa laṣepọ lai mọ.
 
Asiko ti wọn ni iyawo Ukeme ko si nile lo raaye ki ọmọ naa mọlẹ, to si fipa ja ibale rẹ, nibi to ti ko ibasun fun un karakara, ṣugbọn nigba ti aṣiri naa tu, awọn ọlọpaa ẹkun Akodo ni wọn pada lọ fa a le lọwọ.
 
Ohun ti a gbọ ni pe iya ọmọdebinrin, ọmọ ọdun mẹtala yii lo lọ fa ọmọ rẹ le iyawo Ukeme, iyẹn Arabinrin Mary Sunday lọwọ lati maa wo o, iyẹn lagbegbe Idaso to wa nilu Ibẹju Lẹkki, ipinlẹ Eko.
 
Wọn ni irin ajo ọsẹ mẹta pere ni iya ọmọ yii lọ, igba ti yoo si pada de ni ọmọ rẹ sọ fun un pe Ukeme ti fipa ja ibale oun, to si tun n dunkoko lati pa oun danu, boun ba tu aṣiri naa sita.
 
Loju ẹsẹ ni wọn sọ pe iya ọmọ naa ti sare gba teṣan ọlọpaa lọ, iyẹn lọjọ kẹrin oṣu to kọja. Obinrin naa sọ pe nnkan bi aago mọkanla aabọ alẹ, ogunjọ oṣu kẹsan ni Ukeme fipa ba ọmọ oun laṣepọ lasiko ti iyawo ẹ, Mary ti lọ si iṣọ oru.
 
Adekunle Ajiṣebutu to jẹ alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko sọ pe Ukeme ti wa ni ileeṣẹ wọn to wa ni Panti, nibi ti iwadii ti n lọ, ko to di pe wọn foju ẹ ba ile ẹjọ.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI