Apapọ ẹgbẹ awọn ọba alaye lagbegbe Badagry nipinlẹ Eko ti sọ pe Aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu lawọn fọwọ si fun ipo aarẹ orilẹ ede Naijiria lọdun 2023, nitori pe oun lẹni to kaju oṣuwọn.
Wọn sọ pe Aṣiwaju Tinubu ti ẹnikan ṣoṣo to kaju oṣuwọn lati gba ipo aarẹ lọwọ Aarẹ Muhammadu Buhari lọdun 2023.
Nibi ipade kan ti ẹgbẹ South West Agenda (SWAGA’23) ṣagbatẹru rẹ lọjọ Aiku, Sannde ana, ni wọn ti sọrọ yii sita, ti wọn si lawọn ti ṣetan lati gbaruku ti gomina tẹlẹri nipinlẹ Eko naa.
Lara awọn ọba to wa nibẹ ni: Ọba Mọmọdu Afọlabi, Onijanikin tilu Ijanikin; Ọba Nọfiu Dada, Elete tilu Ete; Ọba Abideen Adekanbi, Osolu tilu Osolu; Ọba Mobadenle Oyekan, Onilado tilu Ilado; Ọba Caleb Adeniyi, Ọlọjọ tilu Ọjọ; Ọba N. A. Akinyẹmi, Alabirun tilu Ikarẹ.
Awọn miiran ni: Ọba Taofik Adegboyega, Alahun tilu Imore Apapa; Ọba Gausu Rasak Ovaria tilu Ibeshe; Ọba Kasumu Kosọkọ, Ẹlẹkunpa tilu Ẹkunpa; Ọba Musiliu Adio Yussuf, Oniṣiwọ tilu Tarkwa Bay; Ọba Ọlayinka Lateef, Alado tilu Ado.
Awọn yooku ni: Ọba Adeṣina Aṣade; Oniba Ẹkun tilu Iba; Ọba Ṣhẹrif Adeṣina Bello, Onigbanko tilu Igbanko; ati Ọba Josiah Ilemobade Aina, Ọlọtọ tilu Ọtọ.
Nigba to n sọrọ, alaga ẹgbẹ SWAGA’23 lapapọ, Sẹnetọ Dayọ Adeyẹye dupẹ pupọ lọwọ awọn ọba alaye naa, to si ni yoo dara bi wọn ba pin ipo aarẹ naa silẹ Yoruba, nitori pe ijọba Buhari yoo pari ninu oṣu karun-un, ọdun 2023.
Adeyẹye ninu ọrọ rẹ, sọ pe ọrọ Aṣiwaju Tinubu ti kọja ọrọ ipinlẹ Eko nikan, nitori pe pupọ awọn ẹgbẹ oṣelu kaakiri ipinlẹ Ogun, Ọyọ, Ọṣun, Ekiti ati Ondo ni wọn ti fontẹ lu Tinubu.
No comments:
Post a Comment