Wọ́n ju gbajúmọ̀ Àáfà tó fi orúkọ Buhari lu jìbìtì sẹ́wọ̀n ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n n'Ílọrin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉFriday, October 1, 2021

Wọ́n ju gbajúmọ̀ Àáfà tó fi orúkọ Buhari lu jìbìtì sẹ́wọ̀n ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n n'Ílọrin


Ile-ẹjọ giga tipinlẹ Kwara, eyi to wa nilu Ilọrin ti ju gbajumọ Aafa kan, Jamiu Isiaka sẹwọn ọdun mejidinlọgbọn, lori ẹsun wi pe o lo orukọ Aarẹ Muhammadu Buhari lati fi lu ọmọ orilẹ-ede South Korea kan, ni jibiti obitibiti owo.
 
Keun Sig Kim lorukọ ẹni ti wọn sọ pe Jamiu lu ni jibiti owo ti ko din ni ọgbọn miliọnu naira, pẹlu ẹtanjẹ wi pe yoo gba aṣẹ lati maa ra epo rọbii lorilẹ-ede yii.
 
AWIKONKO gbọ pe Jamiu tun lo orukọ agbẹnusọ Aarẹ Buhari lori ọrọ iroyn, Ọgbẹni Fẹmi Adeṣina ati orukọ alakoso ileeṣẹ NNPC tẹlẹri, Maikanti Baru lati fi lu Kim ni jibiti naa.

Nigba to n jẹwọ ẹṣẹ rẹ, Jamiu sọ pe lara owo toun gba lọwọ Kim loun fi etutu ki aṣiri ma ba tu sita, lai mọ pe ṣe loun n tan ara oun, to si lọwọ EFCC to n gbogun ti iwa jibiti lo tẹ oun lojiji.
 
Onidajọ Mahmud Abdulgafar nigba to n gbe idajọ kalẹ sọ pe ki Jamiu lo fi ọdun mejidinlọgbọn naa kẹkọọ nipa bi eeyan ṣe n ṣiṣẹ ri owo lai lu jibiti.
 
Bẹẹ lo tun paṣẹ pe gbogbo dukia ti wọn gba lọwọ Jamiu patapata loun gbẹsẹ le, nitori pe owo jibiti lo fi ko wọn jọ, to si ni ki ajọ EFCC ta wọn lati fi da owo Kim pada.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI