AbdulRazaq n wá ọ̀nà láti ṣàtúnṣe ètò ọrọ̀ ajé ìpínlẹ̀ Kwara lọ́nà ìgbàlódé - Onímọ̀-ẹ̀rọ Adéyẹmí Balógun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, November 26, 2021

AbdulRazaq n wá ọ̀nà láti ṣàtúnṣe ètò ọrọ̀ ajé ìpínlẹ̀ Kwara lọ́nà ìgbàlódé - Onímọ̀-ẹ̀rọ Adéyẹmí Balógun


Onimọ-ẹrọ Nurudeen Adeyẹmi Balogun ti sọ pe gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq n wa gbogbo ọna lati jẹ ki eto ọrọ ajẹ ipinlẹ naa ba ti igbalode mu, ko si le maa figagbaga pẹlu awọn ipinlẹ to ti ni idagbasoke lẹka eto ọrọ aje. 
 
Nibi ifilọlẹ ileeṣẹ ti wọn ti fẹẹ maa ri sọrọ idagbasoke araalu lọna igbalode, iyẹn ENACT Innovation Hub ti wọn ṣẹṣẹ kọ silu Ajaṣẹ Ipo, ijọba ibilẹ Irẹpọdun.

Ninu ọrọ Gomina AbdulRazaq lo ti sọ pe kikọ agbegbe imọ ayelujara yii tun jẹ atẹgun fun idagbasoke nitori pe yoo ko ipa rere ati ribiribi nigbesi aye awọn araalu kaakiri.
 
Gomina AbdulRazaq dupẹ gidi lọwọ Onimọ-ẹrọ Nurudeen Adeyemi fun akitiyan rẹ lati mu idagbasoke lọna igbalode wọle sipinlẹ naa, ati jijẹ kawọn araalu, paapaa awọn ọdo jẹ anfaani.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI