Ọọni Ile-Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi naa ti wa lara awọn agba ọba alaye ti wọn gboye Ọmọwe bayii, pẹlu fasiti Afẹ Babalọla to wa nilu Ado-Ekiti, ipinlẹ Ekiti ṣe fi oye Ọmọwe daa lọla.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ọjọ Aiku, Sannde to kọja yii ni Ọọni gba iwe-ẹri oye naa, iyẹn Degree of Doctor of Letters, Honoris Causa.
Nibi ayẹyẹ ọdun mejila ti wọn da fasiti naa silẹ, ati ikẹkọọ-gboye ọdun kẹsan-an ni Ọọni Ile-Ifẹ ti fi itan tuntun balẹ.
No comments:
Post a Comment