Akọni títí láí ni Lawal jẹ́ fáwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Kwara - Gómìnà AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, November 15, 2021

Akọni títí láí ni Lawal jẹ́ fáwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Kwara - Gómìnà AbdulRazaq


Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ti sọ pe titi lai ni gomina tẹlẹri nipinlẹ naa, Oloogbe Mohammed Lawal yoo maa jẹ akọni awọn eeyan, pẹlu bo ṣe mu ọrọ igbaye-gbadun araalu lokukudun lakooko to fi wa lori iṣakoso ipo gomina.

Ọjọ Aiku, Sannde, anaa ni Gomina AbdulRazaq sọrọ naa jade, nibi eto iranti ọdun kẹẹdogun to jade laye, to si lawọn yoo maa fi imọriri han si gomina tẹlẹri naa, ni gbogbo igba, nitori pe ọrẹ araalu ti ko ṣee gbagbe titi lai ni, ti orukọ rẹ yoo si wa ninu itan awọn to ti ṣe daadaa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI