Ìjọba Kwara yan ìgbìmọ̀ tí yóò ṣàkóso ilé-ẹ̀kọ́ Kéú tuntun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, November 15, 2021

Ìjọba Kwara yan ìgbìmọ̀ tí yóò ṣàkóso ilé-ẹ̀kọ́ Kéú tuntun


Ijọba ipinlẹ Kwara ti yan igbimọ ẹlẹni meje tuntun kan ti yoo maa ṣakoso ile-ẹkọ Keu, iyẹn Arabic Education Board nipinlẹ naa, eyi ti Ọjọgbọn Mashood Mahmud ti fasiti ipinlẹ Kwara jẹ alaga rẹ.

Lara awọn igbimọ naa ni awọn ọjọgbọn lẹka imọ kuraani, eto ẹkọ ati olori agbegbe wa.
 
Ọmọwe Ahmad Abubakar Agbaje to n ṣoju gbogbo awọn alakoso ile-ẹkọ Keu; Hajia Arabiat Hussein; Abdullahi Muhammad Namallam to n ṣoju ẹgbẹ awọn olukọ (NUT); Hajia Hafsat Titi Oloriẹgbẹ-Alao; Mumini Adebimpe toun n ṣoju ileeṣẹ eto idajọ; ati Abbas Nurein Sunkanmi (akọwe igbimọ) ni wọn jọ wa ninu igbimọ naa. 

Gbigbe ti wọn gbe igbimọ ẹlẹni meje yii dide lo lọ nibamu pẹlu bi igbimọ tijọba be dide lati ṣewadi ohun to n ṣẹlẹ nile-ẹkọ keu ti Ganmo, iyẹn Ganmo Arabic school, eyi ti iwadii rẹ pari lọsẹ meji sẹyin.
 
Igbimọ naa ni yoo bojuto, ti wọn yoo si ṣagbeyẹwo bi ijiya ati nnkan ṣe n lọ si ni gbogbo ile-ẹkọ keu to wa kaakiri ipinlẹ naa, lati ṣe atunṣe to ba yẹ lee lori.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI