Gomina ipinlẹ Edo, Godwin Ọbasẹki, ti jẹ ko di mimọ nita gbangba wi pe oun ko ṣetan lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu miran, bẹẹ si loun tun ti dẹkun lati maa sọ ipinnu ati igbesẹ iṣẹ idagbasoke fun ipinlẹ naa sita.
Nibi akanṣe eto ọlọdọọdun kan ti wọn pe ni Alaghodaro Summit ni Gomina Ọbasẹki ti sọrọ naa sita, to si lawọn ẹgbẹ oṣelu kan ti wọn n wa bẹ oun lati darapọ mọ wọn.
O loun to ṣe pataki soun ni igbe aye ilọsiwaju, nibi ti gbogbo araalu yoo ti maa gbe igbe aye ayọ ati alaafia ti ko labawọn.
Nibi eto ọhun to waye lanaa, ọjọ Abamẹta, Satide, eyi to pe akọle rẹ ni 'Mi o ni ipinnu lati kuro ninu ẹgbẹ oṣelu kan bọ sibomiran' {‘I’ve no plans to switch parties, says Obaseki’}, Ọbasẹki ṣeleri wi pe oun ko le fẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP silẹ bọ sibomiran.
O tẹsiwaju nibẹ pe oun yoo maa tẹsiwaju lati maa ṣe adari gidi fawọn eeyan ipinlẹ Edo, awọn ko si nilo lati kuro ninu ẹgbẹ kan lọ sinu ẹgbẹ miran ki wọn to le ṣiṣẹ idagbasoke.
No comments:
Post a Comment