Gomina tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APGA nipinlẹ Anambra, Ọjọgbọn Chukwuma Charles Soludo ti gba iwe ẹri 'moyege', iyẹn Certificate of Return lọwọ ajọ eleto idibo orilẹ-ede yii.
Ọjọgbọn Charles Soludo ati igbakeji rẹ ti wọn jọ dibo yan, Ọmọwe Onyeka Ibezim, la gbọ pe wọn jọ gba iwe ẹri naa lọjọ Ẹti, Furaide, to kọja yii nilu Awka.
Nigba to n fa iwe ẹri naa le wọn lọwọ, alaga ajọ INEC to dari eto idibo naa, Ọgbẹni Festus Okoye, ṣalaye pe idibo naa ṣoju ṣaara, lo jẹ kawọn kede rẹ gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori.
No comments:
Post a Comment