Mo ti ṣàbẹ̀wò ìbánikẹ́dùn sí Pasitọ Odukọya tí ìyàwó rẹ̀ kú láìpẹ yìí - Bàbá Adébóyè - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, November 15, 2021

Mo ti ṣàbẹ̀wò ìbánikẹ́dùn sí Pasitọ Odukọya tí ìyàwó rẹ̀ kú láìpẹ yìí - Bàbá Adébóyè


Olori ijọ Ridiimu kaakiri agbaye, Pasitọ Enoch Adejare Adeboye ti sọ ọ di mimọ wi pe oun ti ṣabẹwo ibanikẹdun si ọkan lara awọn ọmọ oun, Pasitọ Taiwo Odukọya to padanu iyawo rẹ lọsẹ to kọja.
 
Ori ikanni ayelujara ti Fesibuuku ni Pasitọ Adeboye ti jẹ ko di mimọ, oun ko le ṣai ma lọ ba ọkunrin naa kẹdun iyawo rẹ, Nomthi Odukọya, ati pe awọn tun n dunnu wi pe ọrun rere lobinrin naa wa bayii.

Baba Adeboye sọ pe bi obinrin naa ṣe fi ara rẹ jin fun iṣẹ Ọlọrun to, awọn ko le beere idi ti Ọlọrun fi tete pe e sọdọ. 

Siwaju sii lo gbadura fun idile Odukọya ati ṣọọṣi naa

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI