Ìpínlẹ̀ Ògùn, Amosun, OGD, Aina bá ẹgbẹ́ akọ̀ròyìn nìpínlẹ̀ náà kẹ́dùn ikú alága wọn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, November 16, 2021

Ìpínlẹ̀ Ògùn, Amosun, OGD, Aina bá ẹgbẹ́ akọ̀ròyìn nìpínlẹ̀ náà kẹ́dùn ikú alága wọn


Ijọba ipinlẹ Ogun labẹ akoso Gomina Dapọ Abiọdun; gomina ana, Sẹnetọ Ibikunle Amosun; gomina tẹlẹri, Ọtunba Gbenga Daniẹl ati Amofin Fẹmi Aina ti ba ẹgbẹ akọroyin nipinlẹ naa kẹdun iku alaga wọn, Kọmureedi Olusọji Samson Amosu to jade laye lọjọ Aiku, Sannde, ijẹta.
 
Ninu atẹjade ibanikẹdun ti ijọba ipinlẹ Ogun fi ranṣẹ sẹgbẹ akọroyin, eyi ti kọmiṣanna fọrọ eto iroyin, Ọgbẹni Waheed Oduṣile bu ọwọ lo ti sọ pe ẹdun ọkan nla niku ọkunrin naa jẹ fun wọn.
 
Oduṣile ni ojiji ni iroyin iku naa ba wọn, eyi to ja wọn laya gidi, to si mi gbogbo ipinlẹ Ogun titi. O ṣapejuwe Amosu gẹgẹ bi oniwa irẹlẹ, oniwa tutu bi adaba, ati akikanju ọkunrin ti Ọlọrun fun lẹbun pupọ.

Bakan naa lo sọ pe oloogbe naa ṣunmọ ijọba ipinlẹ Ogun gidi, ti wọn si ni ibaṣepọ to dan mọnran nigba aye ẹ, ati pe o tun ṣiṣẹ takuntakun lati rii pe ibaṣepọ to lọọrin wa laaarin ijọba atawọn akọroyin kaakiri ipinlẹ naa.
 
Ninu lẹta ibanikẹdun tirẹ, gomina ana nipinlẹ Ogun, Sẹnetọ Ibikunle Amosun, ẹni to tun jẹ Sẹnetọ to n ṣoju ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ naa sọ pe oun ko le tete gba iroyin naa gbọ, afigba toun bẹrẹ sii aridaju to ya oun lẹnu.
 
Amosun ninu ọrọ rẹ sọ pe iku Amosu kii ṣe adanu nla fun mọlẹbi rẹ nikan, bi ko ṣe gbogbo fun gbogbo ọmọ ẹgbẹ akọroyin lorilẹ-ede naijiria, paapaa julọ, nipinlẹ Ogun.
 
O ni ọkunrin naa lo ẹkọ iṣẹ naa daadaa, to si fi iwa ọmọluabi ṣe nigba aye ẹ, ati pe o fi han daju gidi pe aṣiwaju to ṣee tẹle loun.
 
Ọtunba Gbenga Daniẹl ninu ọrọ tirẹ naa ṣapejuwe Amosu gẹgẹ bi ẹni toun ko le gbagbe laye, nitori pe awọn jọ ni ibaṣepọ to dan mọnran, ati pe awọn jọ ni iru igboya kan naa.
 
Siwaju sii lo sọ pe o ṣe oun laanu wi pe oṣu meji sẹyin ni ko ba jẹ ọjọ tawọn jọ foju kan ara gbẹyin nigba to wa si ọfiisi oun lati jọ fọrọ jomitoro ọrọ, ṣugbọn toun ko si nile lọjọ naa.
 
Amofin Fẹmi Aina, alaṣẹ ati oludasilẹ iwe iroyin The Village News naa fi atẹjade ibanikẹdun rẹ ranṣẹ sẹgbẹ awọn akọroyin nipinlẹ Ogun, to si ni ọrẹ timọtimọ latilẹ lawọn jọ jẹ, nitori pe awọn jọ lọ ile-ẹkọ alakọbẹrẹ kan naa ni.
 
Aina sọ pe ipa ribiribi ni Amosu ko nigba to n ṣiṣẹ nileeṣẹ iwe iroyin Village News oun gẹgẹ bi aṣojukọroyin, eyi ti ko jẹ koun tii mọ ipo toun wa latigba ti iroyin naa ti tẹ oun lọwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI