Nítorí ọgọ́rùn-ún náírà, ọlọ́pàá gún awakọ̀ Kẹ̀kẹ́ Márúwá pa l'Ékòó - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, November 4, 2021

Nítorí ọgọ́rùn-ún náírà, ọlọ́pàá gún awakọ̀ Kẹ̀kẹ́ Márúwá pa l'Ékòó


Bo tilẹ jẹ pe titi di asiko ti a ṣakojọpọ iroyin yii tan ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ki tii sọrọ lori iṣẹlẹ naa, sibẹ, ibanujẹ niṣẹlẹ ọhun n jẹ fawọn ara agbegbe Ile-Iwe to wa ni Abule-Egba, ipinlẹ Eko, iyẹn lori bi wọn ṣe ni ọlọpaa kan gun oni Kẹkẹ Maruwa pa.
 
AWIKONKO gbọ pe ko si nnkan meji to jẹ ki ọlọpaa naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Olu ṣe gun oni Kẹkẹ Maruwa naa ti wọn pe ni Ibrahim, ẹni tọpọ awọn eeyan mọ si Elẹyẹle pa, bi ko ṣe ti owo riba, ọgọrun-un naira ti wọn lo kọ lati fun un.
 
Gẹgẹ bi awọn to fi iṣelẹ naa to AWIKONKO leti ṣe ṣalaye, wọn ni kii ṣe akọkọ ree tawọn ọlọpaa to wa lagbegbe naa yoo maa gba owo lọwọ awọn ọlọkada atawọn oni Kẹkẹ Maruwa ti wọn n kọja, to si ti di iṣe wọn.
 
Wọn ni akoko ti Elẹyẹle n kọja lọ ni ọlọpaa naa daa duro lati beere owo lọwọ ẹ, ti wọn si niyẹn loun ko lowo lọwọ, ati pe oun ṣẹṣẹ jade ni.
 
Gbogbo akitiyan ti wọn ni ẹni to wa Maruwa naa ṣe lati ṣalaye wi pe ko tii sowo lọwọ oun, ni wọn lo bọ si ẹyin eti ọlọpaa naa, ti wọn ni ṣe lo gba a si ibinu.
 
Lojiji la gbọ pe ọlọpaa naa fa irin kan yọ, to si fi gun oni Kẹkẹ Maruwa naa ni aya, loju ẹsẹ ni ẹjẹ ti bẹrẹ sii da lara rẹ. Ki oloju to o ṣẹ ẹ, wọn ni ọlọpaa naa ti juba ehoro, ki awọn ara agbegbe naa ma ba a dana iya fun un.
 
Wọn ni kawọn eeyan to mọ ohun to ṣẹlẹ, Elẹyẹle ti gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra, to si ti ku, to si jẹ pe fun bi wakati kan si meji ni oku rẹ fi wa nilẹ ko to di pe wọn gbe e lọ si mọṣuari.
 
Bo tilẹ jẹ pe DPO ọlọpaa ti ẹkun Meiran, Toyọsi Ṣokunbi kọ lati sọrọ lori iṣẹlẹ naa, ṣugbọn ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Ogbẹni Adekunle Ajiṣebutu fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, to si ni iwadii ti n lọ lọwọ lori ẹ.
 
Ju gbogbo rẹ lọ, inu awọn ara agbegbe yii ko dun rara si iwa ti wọn ni ọlọpaa naa wu, ti wọn si n beere pe afi ki ileeṣẹ ọlọpaa foju rẹ ba ile ẹjọ, ko si gba idajọ to tọ si i.
 
Wọn n bẹbẹ pe ki ileeṣẹ ọlọpaa ma ṣe dọwọ bo iṣẹlẹ naa mọlẹ, i wọn si gbe igbesẹ to tọ lori ẹ ni kiakia.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI