Ó ku díẹ̀ kí arẹwà ọlọ́mọge ṣe ìgbéyàwó ló bá kàgbákò ikú òjijì sínú ilé alájà mọ́kànlélógún tó wó lulẹ̀ l'Ékòó - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, November 5, 2021

Ó ku díẹ̀ kí arẹwà ọlọ́mọge ṣe ìgbéyàwó ló bá kàgbákò ikú òjijì sínú ilé alájà mọ́kànlélógún tó wó lulẹ̀ l'Ékòó


Lara awọn iwadii to n lọ lọwọ lori ile alaja mọkanlelogun to wo lulẹ l'Ekoo lojiji ti fidi rẹ mulẹ wi pe ọdọmọbinrin, ọmọ ọdun mẹrindinlọgbọn kan, Onyinye Enekwe, naa wa lara awọn to ba iṣẹlẹ ọhun lọ.
 
AWIKONKO gbọ pe oṣu kejila, ọdun yii ni Onyinye fẹẹ ṣe igbeyawo pẹlu ololufẹ rẹ, ti ipalẹmọ si ti fẹẹ pari, koda, wọn ti file po ọti, ti wọn ti fi ọna roka lori ọjọ naa.
 
Ṣugbọn to jẹ pe ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ọjọ kin-in-ni, oṣu kọkanla lo gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra nibi ijamba naa.
 
Ko tii ju ọsẹ meji lọ ti wọn sọ pe Onyinye bẹrẹ iṣẹ gẹgẹ bi amugbalẹgbẹ nileeṣẹ naa, toun naa pẹlu bawọn ku nibẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI